ÈTÒ Ẹ̀KỌ́ ÌGBÀLÓDÉ: ỌNỌREBU OLUMIDE ỌṢỌBA TÚN ṢE BẸBẸ, Ó KỌ́ KÍLÁÀSÌ TUNTUN F'AWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, September 23, 2020

ÈTÒ Ẹ̀KỌ́ ÌGBÀLÓDÉ: ỌNỌREBU OLUMIDE ỌṢỌBA TÚN ṢE BẸBẸ, Ó KỌ́ KÍLÁÀSÌ TUNTUN F'AWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́


Ṣe ni ìdùnnú tún ṣubú lu ayọ̀ àwọn ará agbegbe ìjọba ìbílẹ̀ Abẹ́òkúta North, Ọbafẹmi Owode àti Ọdẹda nígbà tí Ọnọrebu tó lọ ṣojú wọn n'ilu Abuja, Ọnọrebu Olumide Ọṣoba sì àwọn kíláàsì tuntun pẹ̀lú yàrá imọ ẹ̀rọ ìgbàlódé, ìyẹn ICT Centres fún wọn.

Laipẹ yìí ni Ọnọrebu Ọṣọba to jẹ́ ọmọ gómìnà tẹ́lẹ̀rí nipinlẹ Ogun, ìyẹn Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba ṣí àwọn kíláàsì náà fún lílò àwọn akẹ́kọ̀ọ́.



Ki i ṣe àkọ́kọ́ rèé tí Ọnọrebu Olumide Ọṣọba yóò máa ṣe irú àwọn àkànṣe iṣẹ báyìí, AWIKONKO gbọ pé àwọn àkànṣe iṣẹ́ tí kò dín ni ogún lo tí ṣí káàkiri àwọn àgbègbè tó ń ṣojú láàárín ọdún kan tó dé ipò náà. 

AWIKONKO gbọ pé èyí kò jẹ tuntun fún Ọnọrebu Ọṣọba nítorí pé lára àwọn ìlérí rẹ lásìkò ìpolongo ìbò ni ìdàgbàsókè eto ẹ̀kọ́ wá, pàápàá bí ọjọ́ ọ̀la àwọn ọmọdé ṣe jẹ́ pàtàkì sì í. 


Lára àwọn ìlérí rẹ ni Atunkọ àwọn iléèwé tó ti dẹnukọlẹ, ṣiṣoju àwọn aráàlú lọ́nà tó yẹ, irolagbara àti gbígbé àwọn ètò iwuri kalẹ fáwọn èèyàn rẹ. 

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi tí wọn tí ṣí yàrá imọ ẹ̀rọ ìgbàlódé, ìyẹn ICT Centre ni ile ẹ̀kọ́ gírámà tí Ansar-Ud-Deen tó wà ní Iṣaga-Orile, Ọba Ọladele Tella tó jẹ́ Oniṣaga tilu Iṣaga sọ pé ẹ̀bùn ńlá táwọn kò lè gbàgbé ni Ọnọrebu Olumide Ọṣọba fi tà wọn lọrẹ. 


Bákan náà làwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ African Primary School náà fò fún ayọ̀ nígbà tí wón ṣí yàrá ikẹkọọ fún wọn pẹlu awọn ohun amayedẹrun. 

Lára àwọn àkànṣe iṣẹ mi ín ní ti kíláàsì African Church Grammar School, Ita-Eko; ICT Centre tí wọn kọ sí Kọbapẹ Community High School, in Kọbapẹ àtàwọn mi ín. 


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI