ỌLỌPAA MẸTA F'OJU TO N F'ORUKỌ EFCC LU JIBITI BA ILE-ẸJỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, September 25, 2020

ỌLỌPAA MẸTA F'OJU TO N F'ORUKỌ EFCC LU JIBITI BA ILE-ẸJỌ


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Imo ti f'oju awọn ọlọpaa mẹta kan ti wọn ti le danu lẹnu iṣẹ ba ile ẹjọ lori ẹsun wi pe wọn n fórukọ awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ to n gbogun ti iwa ajẹbanu, iyẹn EFCC lu jibiti.

Ọjọbọ, Tọside ana l'awọn ọlọpaa mẹta naa f'oju ba ile ẹjọ, ti wọn si ti wa latimọle bi ẹ ṣe n ka iroyin yii.

Ohun ti a gbọ pe ni pe, ṣe l'awọn ọlọpaa naa n kaakiri lati maa mu awọn afurasi ọmọ Yahoo, ti wọn si n gba owo lọwọ wọn pẹlu ẹtanjẹ wi pe awọn n ṣiṣẹ fun ileeṣẹ EFCC.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Imo, Isaac Akinmoyede n'igba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa sọ pe yatọ si pe wọn n gba owo lọwọ awọn alaiṣẹ, bẹẹ ni wọn tun n gba dukia wọn bi i foonu at'awọn nnkan mi in lọna ti ko ba ofin mu, to si loun ko le laju silẹ ki wọn ba orukọ ileeṣẹ ọlọpaa jẹ.

AWIKONKO gbọ pe awọn ọlọpaa mẹta naa ti wa lahamọ pada n'igba ti wọn ni ile ẹjọ ko jokoo.

Siwaju si i ni Akinmoyede jẹ ko di mimọ pe ọlọpaa ti ko din ni mọkanla l'awọn ti le danu lẹnu iṣẹ, to si l'awọn mọkandinlogun ṣi wa nibi ti wọn ti n ṣe iwadii wọn lori ẹsun aṣemaṣe ti wọn fi kan wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI