GENDEKUNRIN DERO ATIMỌLE ỌLỌPAA NITORI ỌMỌ BUHARI TO FẸẸ FẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 5, 2020

GENDEKUNRIN DERO ATIMỌLE ỌLỌPAA NITORI ỌMỌ BUHARI TO FẸẸ FẸ

Ọmọkunrin ti ẹ n wo yii lo pinu lati gba ẹmi ara rẹ nitori to ni Hannan, ọmọ Aarẹ Muhammadu Buhari ko fi oun ṣe ade ori, ti ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa si tẹ ẹ.

Ipinlẹ Kano ni ọmọkunrin naa to n jẹ Abba Ahmed ti kọ ọ sori ikanni ayelujara rẹ wi pe oun ṣetan lati gba ẹmi ara oun nitori ifẹ t'oun ni si Hannan to ṣe igbeyawo laipẹ yii.

Abba, ọmọ ọdun mejilelogun la gbọ pe ẹka ikẹkọọ imọ iṣiro lo wa ni fasiti Yusuf Maitama Sule t'ilu Kano. Bo ṣe kọ ọrọ naa sori ikanni ayelujara l'awọn ọmọ Naijiria ti bẹrẹ si i gbe kaakiri, ti ọrọ naa si tẹ agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa orilẹ-ede yii, Frank Mba lọwọ.

Frank Mba lo fi to kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Kano, Habu Sani leti, ti wọn fi lọ gbe Abba nibi to wa.

Bi wọn ṣe gbe e ni wọn ti gba a nimọran pe ẹni to loun nifẹ si ko ri tiẹ ro, koda, ti wọn ni Hannan ko mọ Abba ri nibikankan.

Nigba ton sọrọ, Abba ni inu oun dun fun amọran ileeṣẹ ọlọpaa, koda, to tun sọ pe oun ko mọ pe bayii ni awọn ọlọpaa ri, to si mu ko pinu lati darapọ mọ ileeṣẹ ọlọpaa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI