ỌPẸ O! ÌYÀWÓ IGBAKEJI GÓMÌNÀ KWARA NÁÀ TÚN BỌ́ LỌ́WỌ́ KORONAFAIRỌỌSI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 5, 2020

ỌPẸ O! ÌYÀWÓ IGBAKEJI GÓMÌNÀ KWARA NÁÀ TÚN BỌ́ LỌ́WỌ́ KORONAFAIRỌỌSI


Bí kí í bá a ṣe àdúrà àwọn olólùfẹ́ ìyàwó igbá-kejì Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara, Arábìnrin Abieyuwa Alabi ni, ó ṣeé ṣe kí orin ọpẹ táwọn èèyàn ń kọ lásìkò yìí má rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú bo se ja ajabọ lọ́wọ́ ajakalẹ àrùn COVID-19. 

Ní nǹkan bí ọsẹ mélòó kan sẹ́yìn ni ìròyìn náà jáde síta wí pé igbá-kejì gómìnà, Ọgbẹni Kayọde Alabi àti ìyàwó rẹ, Arábìnrin Abieyuwa Alabi náà tí pẹ̀lú àwọn tó lugbadi àrùn yìí. 

AWIKONKO náà gbé ìròyìn yìí sí í yín létí nígbà náà, tí a sì sọ pé inú aawẹ àti àdúrà làwọn èèyàn wa. 

Ọ̀sẹ̀ tó lọ yìí ni a tún gbé sì í yín létí pé ara igbá-kejì gómìnà tí yá, tòun sì ti ń jáde síta bí í tí tẹ́lẹ̀. 

Ṣùgbọ́n ní báyìí, tayọ-tayọ niroyin náà tí a ń mú wá fún un yín báyìí pé ara Arábìnrin Abieyuwa náà tí yà.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI