IJỌBA KWARA B'AWỌN ARAALU KẸDUN LORI OMIYALE TO ṢẸLẸ NILU ILỌRIN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, September 21, 2020

IJỌBA KWARA B'AWỌN ARAALU KẸDUN LORI OMIYALE TO ṢẸLẸ NILU ILỌRIN


Bẹẹ ni wọn ṣeleri iranlọwọ


Ijọba ipinlẹ Kwara ti ṣeleri aabo to peye f'awọn to kagbako iṣẹlẹ omiyale ati iji lile, eyi to waye lọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii nilu Ilọrin.
 
Ko din ni ile aadọta ti iji lile ka orule wọn, ti omi si tun yawọ awọn ile kan, ko da t'awọn ti ko din ni meje tun farapa yannayanna nibi ile to wo naa.
 
Eeyan kan ṣoṣo la gbọ pe omi gbe lọ lagbegbe Lower Taiwo, Ilọrin.

Nigba to n b'awọn eeyan kẹdun ninu atẹjade ibanikẹdun to fi sita l'ọjọ Aiku, Sannde ana, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ni ẹdun ọkan lo jẹ fóun ati pe ijọba ti bẹrẹ igbesẹ lati ran awọn to kagbako ninu ijamba naa lọwọ.
 
Diẹ lara awọn fọto ijamba naa


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI