AWỌN NNKAN TI Ẹ KO GBỌ NIPA ILE ITAJA IGBALODE TO JONA DI EERU L'ABẸOKUTA {FỌTO} - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, September 21, 2020

AWỌN NNKAN TI Ẹ KO GBỌ NIPA ILE ITAJA IGBALODE TO JONA DI EERU L'ABẸOKUTA {FỌTO}

Ko sẹni to de agbegbe kan ti wọn n pe ni Totoro n'ilu Abẹokuta laaarọ ana Sande ti omije ko ni i bọ loju ẹ lori bi ile itaja igbalode tuntun ṣe jona di eeru, t'awọn dukia ati ọja to le ni ẹẹdẹgbẹta miliọnu naira si ṣofo danu.

Nnkan bi aago meje aarọ la gbọ pe ina naa deede ṣẹyọ ninu ile itaja, t'awọn eeyan to n kọja lọ si kọkọ ro pe eremọde ni, ṣugbọn ti ọrọ naa pada yiwọ.

Gẹgẹ bi awọn awuyewuye to tẹ AWIKONKO lọwọ ṣe sọ, wọn ni ọkan lara awọn to ni ṣọọbu igbalode yii ni wọn gbagbe lati pa nnkan ti wọn fi sinu ina, ko to di pe kinni naa gbina lojiji to si ba pupọ dukia jẹ.

Loju ẹsẹ ti wọn l'awọn eeyan ti ri eefin ina to n jati apa oke ile itaja igbalode ti wọn ti n ta awọn ohun elo ile bi i ina at'awọn nkan mi in ni wọn ti ranṣẹ s'awọn oṣiṣẹ panapana n'ipinlẹ Ogun, t'awọn naa si gbiyanju agbara wọn, ṣugbọn ti epa ko boro mọ rara.

Eyi ni fọto bi iṣẹlẹ naa ṣe lọ si i fun igbadun yin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI