Lojuna lati gba gbogbo duki ipinlẹ Kwara pada lọwọ awọn to gba a lọna ayederu, ati lati le ṣe ijọba ojumito f'awọn araalu, ijọba ipinlẹ naa labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti kede sita wi pe awọn ti gba ọkan lara awọn dukia wọn ti ẹgbẹ oṣelu PDP gbẹsẹ le lati bi ọpọlọpọ ọdun sẹyin.
Ọfiisi ẹgbẹ oṣelu PDP to wa ni wọọdu Ubandawaki, ijọba ibilẹ Ilọrin West la gbọ pe ẹgbẹ naa gba pẹlu eru lasiko ti wọn fi wa n'ijọba, ṣugbọn ti Gomina Abdulrazaq ti wa a jẹ ko di mimọ pe ko sẹni to la gbẹsẹ le dukia ijọba lọna ti ko ba ofin mu.
Gẹgẹ bi atẹjade ti akọwe Gomina, Ọgbeni Rafiu Ajakaye fi ṣọwọ s'AWIKONKO laipẹ yii lo ti sọ pe ijọba ti bẹrẹ igbesẹ lati sọ ọ di nnkan t'awọn araalu yoo maa ri lo.
O ni ọfiisi naa ni ijọba Oloogbe Muhammed Lawal kọ lọdun 2003 lati fi ṣe ọsibitu f'awọn araalu, ṣugbọn ti wọn ni ijọba Bukọla Saraki lo fun ẹgbẹ oṣelu PDP lati fi ṣe ọfiisi latari oṣelu ẹtaanu to ṣe pẹlu ijọba Lawal nigba naa.
No comments:
Post a Comment