ABDULRAZAQ BA EL-RUFAI KẸDUN IKU ỌBA ZAZZAU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, September 21, 2020

ABDULRAZAQ BA EL-RUFAI KẸDUN IKU ỌBA ZAZZAUKi i ṣe iroyin tuntun mọ pe Ọba ilu Zazzau, Dọkita Shehu Idris n'ipinlẹ Kaduna ti jade laye, to si ba pupọ awọn eeyan agbegbe naa lọkan jẹ gidi, ṣugbọn l'ọjọ Aje, Sande ana ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq bá Gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna, Nasir El-Rufai kẹdun iku ọba naa.
 
Ninu atẹjade ibanikẹdun ti Gomina AbdulRazaq fi sita lati ọwọ akọwe iroyin rẹ Ọgbẹni Rafiu Ajakaye lo ti jẹ ko di mimọ pe iku naa dun oun pupọ lasiko yii, tosi ni adanu nla lo jẹ.

AbdulRazaq ni gbogbo aaye to ṣi silẹ ni oloogbe naa di patapata nigba aye rẹ, to si n'ọwọ ifẹ si gbogbo awọn to jẹ ọba le lori.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI