NITORI FỌTO IDAJI IHOHO RẸ TO GBE SITA L'ỌJỌ IBI Ẹ, AWỌN EEYAN SỌRỌ BURUKU SI ẸNIỌLA BADMUS - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, September 11, 2020

NITORI FỌTO IDAJI IHOHO RẸ TO GBE SITA L'ỌJỌ IBI Ẹ, AWỌN EEYAN SỌRỌ BURUKU SI ẸNIỌLA BADMUS


Ọlọrun ko ni i jẹ ki abamọ gbẹyin ọrọ wa l'adura t'awọn eeyan maa n gba lojoojumọ, paapaa bi wọn ba fẹẹ gbe igbesẹ kan to ni i ṣe pẹlu itiju.

Ọjọ keje oṣu yii, iyẹn ọjọ Mọnde to kọja yii ni ọkan lara awọn irawọ oṣerebinin ọmọ bibi ipinlẹ Ogun nni, Ẹniọla Badmus ṣe ayajọ ayẹyẹ ọjọ ibi ẹ, t'awọn eeyan, paapaa awọn ololufẹ rẹ si n ki ku oriire jakejado.

Ṣe ni nnkan yiwọ fun Ẹniọla Badmus to tobi gbangba nigba to gbe fọto idaji ihoho rẹ sori ikanni ayelujara ti Instagiraamu, eyi to fi n ki ara rẹ naa ku oriire, n'igba t'awọn eeyan bẹrẹ si i sọrọ buruku si i.

Ki i ṣe ti Ẹniọla ni yoo jẹ akọkọ awọn oṣere tiata ti yoo maa gbe fọto ihoho tabi fọto idaji ihoho wọn sita, t'awọn eeyan si maa n sọrọ buruku si wọn, ti ọrọ Ẹniọla naa ko si yatọ n'igba t'oun naa gbe fọto idaji ihoho ara rẹ sita.

B'awọn eeyan ṣe n sọ pe alainitiju ni Ẹniọla nitori pe oju t'awọn eeyan fi n wo o kọ l'oun fi n wo ara rẹ, ti wọn si lóun naa wa lara awọn oṣerebinrin alaṣẹwo to jẹ pe iṣẹ tiata ni wọn fi n boju.

Fọto naa ree:

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI