WOLII OBINRIN ẸLẸSIN ISLAM, MISTURA AKINTUNDE TU AṢIRI TO WA N'IDI IFIPABANILOPỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, September 11, 2020

WOLII OBINRIN ẸLẸSIN ISLAM, MISTURA AKINTUNDE TU AṢIRI TO WA N'IDI IFIPABANILOPỌ


Kii saba wọpọ ki eeyan ri obinrin Musulumi nita lati maa ṣiṣẹ wolii, gẹgẹ b'awọn obinrin ẹlẹsin Kristẹni ti n ṣe e.

Amọ ti Wolii obinrin Mistura Oseni Akintunde, ẹni to n ṣiṣẹ wolii nilana ẹsin Islam yatọ.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori iwa ifipabanilopọ, Wolii Akintunde ni kii ṣe bi obinrin ba ṣe mura lo n fa iwa ifipabanilopọ, gẹgẹ bi awọn eeyan kan ṣe lero.

Amọ o ṣalaye pe bi a ba ṣe wo ara wa loju si, boya ọkunrin ni abi obinrin lo n fa iwa ifipabanilopọ.

Akintunde fikun pe, kii ṣe awọn ọkunrin nikan lo n huwa ifipabanilopọ, gẹgẹ bi awujọ wa ṣe lero, amọ awọn obinrin gan n fipa bani lopọ, ko si yẹ ka maa pariwo awọn ọkunrin nikan.
 
O wa tako ẹwọn ọdun mejidinlogun ti wọn n fun awọn eeyan to n fipa bani lopọ, eyi to ni ko to fun ijiya ẹṣẹ wọn .

Bakan naa lo rọ awọn eeyan lati ye ko awọn ti wọn ba fi tipa ba lopọ laya jẹ lori ayelujara, amọ n ṣe lo yẹ ki wọn ṣewuri fun wọn lati jade sita sọ tẹnu wọn.

Lati: BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI