O MA ṢE O! AKẸKỌỌ FASITI MEJI PADANU ẸMI WỌN SINU IJAMBA MỌTO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, September 6, 2020

O MA ṢE O! AKẸKỌỌ FASITI MEJI PADANU ẸMI WỌN SINU IJAMBA MỌTO


Meji ninu awọn akẹkọọ fasiti Abubakar Tafawa Balewa to wa n'ilu Bauchi  ni wọn ti padanu ẹmi wọn sinu ijamba mọto lasiko ti wọn n rin irin ajo.
 
Inu odo nla kan la gbọ pe mọto wọn gbokiti wọn n'igba ti ijanu mọto naa deede yọnu lori ere.

Aminu Ahmed ati Abubakar ti wọn ni ipele to gbẹyin (500level) ni ẹka ikẹkọọ imọ-ẹrọ (Electrical/Electronic Engineering) l'awọn mejeeji wa ni wọn padanu ẹmi wọn l'ọjọ Wẹside ati Tọside to kọja yii.

Titi ta a fi kọ iroyin yii tan l'awọn mọlẹbi ati ọrẹ wọn ṣi wa ninu ibanujẹ nla, lori bi wọn n ṣe ori gbogbo ikanni ayelujara lati kẹdun iku wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI