O MA ṢE Ó! Ẹ GBỌ́ NǸKAN TÍ GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ SỌ NÍPA Ọ̀JỌ̀GBỌ́N AKINWALE TÓ D'OLÓÒGBÉ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, September 16, 2020

O MA ṢE Ó! Ẹ GBỌ́ NǸKAN TÍ GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ SỌ NÍPA Ọ̀JỌ̀GBỌ́N AKINWALE TÓ D'OLÓÒGBÉ


Bí gbogbo àwọn èèyàn káàkiri àgbáyé, pàápàá àwọn èèyàn lagboole òṣeré tíátà ṣe n kẹdun iku Ọjọgbọn Ayọ Akinwale, Gomina ipinlẹ Kwara naa AbdulRahman AbdulRazaq ti ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi adanu ti ko ṣee rọpo.
 
Ọjọ Aje, Mọnde ijẹta ni Gomina AbdulRazaq sọrọ naa n'igba to n kẹdun iku Oloogbe Akinwale to jade laye laipẹ yii, ẹni to ti ko ipa ribiribi nidi iṣẹ agbelewo, paapaa l'ẹka eto ẹkọ.
 
Ọdu ni Oloogbe Ọjọgbọn Ayọ Akinwale, ki i ṣaimọ f'oloko lagbọọle amuludun lorilẹ-ede Naijiria, at'awọn agbegbe kan lagbaye, ẹni to jẹ olukọ agba lẹka imọ ẹkọ ere idaraya, iyẹn Department of Performing Arts ni fasiti tílu Ilọrin, ipinlẹ Kwara.
 
Gomina AbdulRazaq ni ọrọ Oloogbe naa jinna patapata si ejo to kọja lori apata, to si dabi ajanaku to gba aarin ilu kọja pẹlu awọn ipa rere to fi silẹ lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI