Bi ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari ko ba tete wa nnkan ṣe sọrọ owo epo rọbi ati ina mọnamọna to lọ soke lojiji lorilẹ-ede Naijiria, afaimọ ni ki omi ma pada tẹyin wọ igbin lẹnu pẹlu b'awọn oṣiṣẹ ṣe l'awọn yoo gbe pẹrẹki kana pẹlu ijọba rẹ.
Ọsẹ meji pere la gbọ pe ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ fun Aarẹ Muhammadu Buhari lati ṣe agbeyẹwo lori ọrọ owo epo rọbi ati ina mọnamọna to lọ soke naa, ki wọn si tete ja a wa silẹ ko too to ọsẹ meji.
AWIKONKO gbọ pe ọjọ kejidinlọgbọn oṣu yii l'awọn oṣiṣẹ l'awọn yoo da iṣẹ silẹ kaakiri orilẹ-ede Naijiria.
Ayuba Wabba to jẹ Aarẹ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lapapọ lo tun f'idi rẹ mulẹ lẹyin ipade ti igbimọ amuṣẹya, iyẹn Central Working Committee ati awọn alakoso, iyẹn National Administrative Council ṣe ipade ni olu ileeṣẹ awọn oṣiṣẹ.
Nibẹ ni Wabba ti jẹ ko di mimọ pe ipade t'awọn ṣe pẹlu ijọba apapọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee ko ti i so eso rere.
O wa ni bi ijọba ko ba fa owo naa sẹyin, awọn yoo bẹrẹ idaṣẹsilẹ kaakiri Naijiria nitori pe inira t'awọn eeyan n jẹ pọ kọja sisọ.
No comments:
Post a Comment