O PARI O! WỌN FẸẸ F'AWỌN AGUNBANIRỌ RỌPO AWỌN DỌKITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, September 11, 2020

O PARI O! WỌN FẸẸ F'AWỌN AGUNBANIRỌ RỌPO AWỌN DỌKITA


Minisita fun eto ilera lorilẹ-ede Naijiria, Ọsagie Ehanire ti paṣẹ fun gbogbo awọn ọga agba at'awọn alabojuto ọsibitu kaakiri orilẹ-ede yii lati gba awọn agunbanirọ sẹnu iṣẹ lori b'awọn dọkita at'awọn oṣiṣẹ eleto ilera ṣe da iṣẹ silẹ lojiji.

Ọsagie ni ko saaye lati maa ba awọn dọkita to da iṣẹ silẹ naa sọrọ titi nitori pe awọn kan wa ti wọn ṣetan lati ṣiṣẹ, ti wọn si ti kẹkọọ gboye ni fasiti, koda, ti wọn tun ti sin orilẹ-ede baba wọn.

O ni ki wọn bẹrẹ iṣẹ ni waranṣeṣa.

L'ọjọ Aje, Mọnde to kọja yii l'awọn dọkita naa da iṣẹ silẹ, n'igba ti wọn sọ pe ijọba apapọ kọ lati fun wọn l'awọn owo to tọ si wọn lori ajakalẹ arun Covid-19 at'awọn ẹtọ mi in ti wọn n beere fun.

Ehanire wa a jẹko di mimọ pe asiko ti orilẹ-ede yii n koju iṣoro nla nipa arun Covid-19 l'awọn dọkita l'awọn n da iṣẹ silẹ, eyi to ni ko bojumu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI