AKEREDOLU DI GOMINA ẸLẸẸKEJI L'ONDO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, October 11, 2020

AKEREDOLU DI GOMINA ẸLẸẸKEJI L'ONDO


Bi ẹ ṣe n ka irtoyin yii, Gomina Rotimi Akeredolu ti pada wọle ẹlẹẹkeji gẹgẹ bi i gomina ipinlẹ Ondo ninu idibo to waye lọjọ Satide-Abamẹta ana.

Bo tilẹ jẹ pe oriṣiriṣi lo ṣẹlẹ nibi eto idibo ti wọn di kaakiri ijọba ibilẹ to wa n'ipinlẹ naa, sibẹ, ibo to pọ rẹpẹtẹ ni Gomina Akeredolu fi bori awọn alatako rẹ yooku.

Ibo 292,830 ni Akeredolu fi n lewaju, to si la alatako rẹ sunmọ ọn lati inu ẹgbẹ oṣelu PDP, Eyitayọ Jẹgẹdẹ toun ni ibo 195,791.

Igbakeji rẹ, Agboọla Ajayi toun gbe apoti labẹ asia ẹgbẹ oṣelu ZLP ni ibo 69,127.

Ijọba ibilẹ mẹẹdogun ninu mejidinlogun ni Akeredolu ti jawe olubori, lara wọn si ni Ile-Oluji/Oke-Igbo, Irele, Akoko Southwest, Akoko Northeast, Akoko Northwest, Ondo East, Owo, Idanre, Akoko Southeast, Akure South, Ondo West, Ose, Ese-Odo ati Ilajẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI