Ẹ WOJU WALE HASSAN TI WỌN JU SẸWỌN ỌDUN MẸWAA L'AMẸRIKA LORI ẸSUN IFIPABANILOPỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, October 10, 2020

Ẹ WOJU WALE HASSAN TI WỌN JU SẸWỌN ỌDUN MẸWAA L'AMẸRIKA LORI ẸSUN IFIPABANILOPỌ


Ọmọ orilẹ-ede Naijiria kan, Ọlawale Hassan ni wọn ti ju sẹwọn ọdun mẹwaa gbako lorilẹ-ede Amẹrika laipẹ yii lori ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan an.
 
Gbajumọ ni Ọlawale Hassan t'awọn ololufẹ rẹ tun n pe ni Goldie 1, olori takasufee ni wọn pe e, ti wọn si lo maa k'ọrin asarekọ, iyẹn Rap. 
 
Ọmọ ọdun mẹtalelọgbọn ni wọn pe e, ti wọn si lo o fipa ba obinrin kan laṣepọ l'ọdun 2017 ni Southend. 
 
Obinrin naa ti wọn ni ọjọ ori ẹ ko ti i kọja ogun ọdun lo fẹsun kan Goldie pẹlu ẹtanjẹ ti wọn lo o ṣe fun un.
 
Wọn ni bo tilẹ jẹ pe Goldie ti sọ pe wọn purọ ẹsun mẹta ti wọn fi kan oun m'oun ni, ṣugbọn ti ile ẹjọ sọ pe ko si awijare kankan lẹnu ẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI