AKEREDOLU YẸYẸ AJAYI NIBI IPADE ALAAFIA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, October 7, 2020

AKEREDOLU YẸYẸ AJAYI NIBI IPADE ALAAFIA


Ọrọ buruku t'oun tẹrin l'ọjọ Iṣẹgun-Tuside ana nibi t'awọn oludije sipo Gomina nipinlẹ Ondo ti t'ọwọ bọ'we adehun wi pe eto idibo to fẹẹ waye l'opin ọsẹ to n bọ yii yoo lọ n'irọwọ-irọsẹ, ko si ni la ariwo lọ.
 
Ajọ eleto idibo ipinlẹ Ondo lo ṣagbatẹru eto naa wi pe ko ni i si wahala kankan laarin awọn oludije at'awọn ọmọlẹyin wọn lasiko ati lẹyin idibo ọjọ Abamẹta-Satide ọsẹ yii.
 
Gẹgẹ bi ohun ti a gbọ, wọn ni ṣe ni oludije sipo Gomina labẹ asia ẹgbẹ Zenith Labour Party, Ọgbẹni Agboọla Ajayi, ẹni to tun jẹ igbakeji Gomina lọwọlọwọ ni Gomina Oluwarotimi Akeredolu yẹyẹ rẹ nibi eto naa.
 
Wọn ni bi awọn oludije sipo Gomina patapatapa ṣe pari titọwọbọ iwe adehun naa tan ni Gomina Akeredolu dide lati bọ gbogbo oludije lọwọ, ti wọn si lo n gbiyanju lati na ọwọ alaafia si gbogbo wọn.
 
AWIKONKO gbọ pe bo ṣe bọ awọn oludije kan, paapaa oludije labẹasia ẹgbẹ oṣelu PDP, iyẹn Eyitayọ Jẹgẹdẹ lọwọ tan ni igbakeji rẹ, Ajayi gbiyanju lati lọ bọ ọ lọwọ, ṣugbọn ti wọn ni kaka ko bọ ọ lọwọ, ṣe lo juwọ si i lọọkan, ti ko si jẹ ko sunmọ ọdọ oun.
 
Gbogbo ohun ti wọn lo o jẹ ero ọkan Akeredolu ni pe ere kini aja n ba ẹkun ṣe, to fi fẹ k'awọn fóju ifẹ han sira wọn nita gbangba lẹyin awọn ọrọ buruku to ti sọ si i kaakiri.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI