IJỌBA KWARA ṢELERI IGBE-AYE ARA-ỌTỌ F'AWỌN OLUKỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, October 7, 2020

IJỌBA KWARA ṢELERI IGBE-AYE ARA-ỌTỌ F'AWỌN OLUKỌ


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ṣeleri fun gbogbo awọn olukọni patapata kaakiri ipinlẹ naa wi pe wọn yoo bẹrẹ si i jẹ igbadun to tọ si wọn.
 
Igbakeji Gomina, Ọgbẹni Kayọde Alabi lo sọrọ naa laipẹ yii nibi ayajọ ọjọ awọn olukọni lagbaye, eyi t'awọn olukọni n'ipinlẹ naa wa lara wọn.
 
O ni gbogbo ohun ti yoo mu igbe aye rọrun f'awọn olukọ jakekado ipinlẹ naa l'awọn yoo ṣe lati le jẹ ki wọn ba ẹgbẹ pe.
 
Nibi eto ọlọdọọdun naa t'ẹgbẹ awọn olukọ, iyẹn National Union of Teachers, ẹka t'ipinlẹ Kwara n'ilu Ilọrin ṣagbekalẹ rẹ lo ti sọ pe gbe oriyin f'awọn olukọ lori iṣẹ takuntakun ti wọn n ṣe lati tọ awọn ọjọ ọla Naijiria sọna to yẹ.

O wa gba wọn lamọran wi pe k'awọn naa gbiyanju lati fara da awọn ipenija ti ajakalẹ arun Covid-19 mu wa sorilẹ-ede Naijiria, paapaa julọ eyi to pọn dandan wi pe ki wọn maa ṣe idanilẹkọọ lori ikanni ayelujara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI