AWỌN ỌLỌPAA LO PURỌ MỌ MI - PASITỌ SUNDAY - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, October 29, 2020

AWỌN ỌLỌPAA LO PURỌ MỌ MI - PASITỌ SUNDAY


Ẹdinọr Sunday ti wọn ko mọ awọn to ji ẹru ijọba ko, paapaa awọn irinṣẹ eto ilera n'ipinlẹ Kogi ti sọ pe awọn ọlọpaa lo parọ mọ oun, tori pe oun ko mọ nnkankan nipa ẹsun ti wọn fi kan oun.
 
 
Awọn mẹrindinlọgọta ni olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ kogi fi han f'awọn oniroyin lana Ọjọru ti i ṣe Wẹside wi pe awọn ti ọwọ palaba wọn segi niyẹ. 
 
Nigba to n sọrọ, Sunday sọ pe oun ko mọ nnkan nipa ẹsun ole ti wọn fi kan oun, tori pe ojiṣẹ Ọlọrun tootọ loun, oun ko si le jale.
 
Ọjọ Aje-Mọnde la gbọ pe awọn araalu lọọ ja ọsibitu kan nípinlẹ naa, ti wọn si ko awọn irinṣẹ to wa nibẹ.
 
 
Pasitọ ṣọọṣi kan to wa ni ikorita ilu Kabba ni wọn pe Sunday. Nigba to si n b'awọn oniroyin sọrọ lo sọ pe awọn tọọgi ni wọn fa wahala, to si mu koun fi mọto oun silẹ salọ. 
 
O nigba ti oun pada lati lọ gbe mọtọ naa kuro nibi to wa ni wọn mu oun, ti wọn si fi ẹsun kan oun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI