AWỌN TỌỌGI GBA FILA LORI FAYOṢE, LO BA PARIWO KI WỌN MA JE K'OUN KU BI I BỌLA IGE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, October 8, 2020

AWỌN TỌỌGI GBA FILA LORI FAYOṢE, LO BA PARIWO KI WỌN MA JE K'OUN KU BI I BỌLA IGE


Gomina ana n'ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Peter Ayọdele Fayoṣe ti pariwo sita wi pe k'awọn ọmọ Naijiria gba oun lọwọ awọn to n lepa ẹmi oun, ati pe ki wọn ma jẹ k'oun ku bi i ti oloogbe Bọla Ige.

Ninu fọnran kan to jade sori ayelujara ni Fayoṣe ti sọrọ yii. Nibi ipolongo ẹgbẹ oṣelu PDP fun ti idibo Gomina ipinlẹ Ondo to n bọ lọna la ti ri i pe bi Fayoṣe ṣe n gbiyanju lati gun ori pepele ipolongo l'awọn kan ti sunmọ ọn, ti wọn si gba fila lori ẹ.

Fayoṣe ni ko ni i ba oju mu t'oun ba ku iru iku Bọla Ige ku. F'awọn to ba ranti daadaa, Aafin Ọọni Ile Ifẹ ni wọn ti gba fila lori Bọla Ige lọjọ kẹtalelogun oṣu kejila ọdun 2001, ti wọn si pada yinbọn pa a lẹyin ẹ sinu ile ẹ to wa ni Bodija n'ilu Ibadan.

Bi wọn ṣe gba fila lori Fayoṣe lo ti sare sọ pe oun yoo jẹ k'awọn ileeṣẹ eleto aabo mọ bi nnkan ṣe lọ si nibi ipolongo idibo naa, to si ni ki i ṣe nnkan to yẹ ki wọn fi ọwọ yẹpẹrẹ mu rara.

Ninu ọrọ agbẹnusọ Fayoṣe, Ọgbẹni Lere Ọlayinka lo ti fẹsun kan gomina tẹlẹri kan, ati igbakeji alaga ẹgbẹ oṣelu PDP tẹlẹri wi pe awọn ni wọn wa nidi bi wọn ṣe gba fila lori Fayoṣe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI