Ẹ GBỌ́ NǸKAN TÍ GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ SỌ NÍPA EMIR ZAZZAU TUNTUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, October 8, 2020

Ẹ GBỌ́ NǸKAN TÍ GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ SỌ NÍPA EMIR ZAZZAU TUNTUN


Kí í ṣe ìròyìn tuntun mọ pe ìjọba ìpínlẹ̀ Kaduna tí yàn Ẹmir tilu Zazzau tuntun. Ọjọru-Wẹside àná ni Gomina Nasir El-Rufai kéde Alaaji Ahmed Nuhu Bamalli gẹ́gẹ́ bí Ẹmir kọkàndínlógún n'ilu Zazzau. 

AWIKONKO gbọ́ pé ọdún marundinlaadọta ni Emir àná, Alaaji Shehu Idris lo lórí ipò gẹ́gẹ́ bí Ẹmir Zazzau kò tó o lọ báwọn bàbà ńlá rẹ. 
 
Gómìnà AbdulRazaq nínú ọ̀rọ̀ rẹ, o ni ẹni tí fìlà ipò náà tọ si ni wọn yàn, tí kì í sì ṣe pé wọn ṣe ojúsàájú. 
 
Ó ní òun kò lè gbàgbé ajọṣepọ tó wà láàárín bàbà Ẹmir tuntun náà, Olóògbé Alaaji Nuhu Bamalli àti bàbà òun, Olóògbé AGF AbdulRazaq. Ó làwọn méjèèjì jọ sìn ìlú Zazzau ni gẹ́gẹ́ bí í Magajin Gari àti Tafida, bẹ́ẹ̀ ni wọn tún jọ wá nínú ìṣàkóso Sir Tafawa Balewa nígbà ayé wọn. 

Gomina AbdulRazaq lòun nigbagbọ pé Emir tuntun náà yóò lo ìrírí àti imọ ẹ̀kọ́ tó ní láti fi mú ìdàgbàsókè tó lọọrin bá ìlú náà, bẹ́ẹ̀ lo gbàdúrà fún un yóò pẹ lórí ipò náà gẹ́gẹ́ bí àwọn bàbà ńlá rẹ. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI