Ajọ to n ṣakoso eto ilara lagbaye, World Health Organizations ti ke gbajare sita wi pe awọn tọọgi ti ji gbogbo awọn irinṣẹ ti wọn n lo lati fi ṣe itọju ajakalẹ arun koronafairọọsi ti wọn tun n pe ni Covid-19 gbe.
Awọn irinṣẹ ti wọn pe ni Personal Protective Equipment {PPE} ni wọn l'awọn tọọgi to n ji awọn ounjẹ konilegbele {Palliatives} gbe.
Alakoso ajọ naa nilẹ Afrika, Dọkita Matshidiso Moeti lo sọ eyi di mimọ lonii Ọjọbọ ti i ṣe Tọside.
Moeti tun ṣalaye pe ohun to n kan oun lominu ni b'awọn eeyan ko ṣe wo awọn atubọtan ajakalẹ arun naa pẹlu bi wọn ko ṣe tẹle awọn ilana lati dẹkun ajakalẹ arun naa.
No comments:
Post a Comment