Aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Muhammadu Buhari ti sọ pe ipo ẹlẹgẹ ni eto ọrọ aje orilẹ-ede yii wa lasiko yii, eyi to ni le faaye silẹ fun isede konilegbele ẹlẹẹkeji iru ẹ.
O wa gba awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria lamọran wi pe ki wọn bẹrẹ si i tẹle awọn ilana ati ofin to rọ mọ didẹkun ajakalẹ arun koronafairọọsi gẹgẹ b'awọn ọjọgbọn lẹka eto ilera ṣe laa kalẹ.
Lonii ni Aarẹ Buhari sọrọ yii lori ikanni ayelujara ti Twitter rẹ, nibi to ti n sọ pe o ṣe pataki fun gbogbo awọn araalu lati tẹle awọn ilana ati alakalẹ awọn eleto ilera lojuna lati dẹkun ajakalẹ arun Covid-19.
O ni pẹlu eyi, yoo jẹ ki ajakalẹ arun naa tete kasẹ nilẹ patapata, ati pe esi t'awọn n gba lẹnu ọjọ meloo kan sẹyin ti n fi han daju pe Naijiria ti n bọ kuro lọwọ arun naa.
No comments:
Post a Comment