ÀYÁJỌ́ ÒMÌNIRA! Ọ̀MỌ̀WÉ FAJẸNYỌ GBÀDÚRÀ F'AWỌN ỌMỌ NÀÌJÍRÍÀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, October 1, 2020

ÀYÁJỌ́ ÒMÌNIRA! Ọ̀MỌ̀WÉ FAJẸNYỌ GBÀDÚRÀ F'AWỌN ỌMỌ NÀÌJÍRÍÀ


Ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ni lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Ọ̀mọ̀wé Olusọji Aderẹmi Fajẹnyọ tí gba àwọn àkànṣe àdúrà fáwọn ọmọ àti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà káàkiri àgbáyé.

Ọ̀mọ̀wé Fajẹnyọ to tún jẹ́ Alakoso ẹ̀ka imọ èdè Yorùbá nílé ẹ̀kọ́ àwọn olùkọ́ni tí kọlẹẹji tilu Abẹ́òkúta, ìyẹn Federal College of Education, Abẹ́òkúta, ìpínlẹ̀ Ogun lo ṣe àdúrà náà laaarọ òní, ọjọ́ kinni oṣù kẹwàá ọdún 2020. 

Èyí ni ẹ̀bẹ̀ àdúrà rẹ sì Elédùmarè 

Oṣù kẹwàá la wọ̀ 
K'Elédùwà fi ohun gbogbo kẹ́ wa 
K'íre wá wa wá 
K'ọ́mọ wá wa wá 
K'ájé wá wa wá 
K'àlàáfíà wá wa wá 
Kí àìkú baálẹ̀ ọrọ̀ wá wa wá 
Èyí a wá wi k'árọ̀ o rọ̀ mọ 
Àṣẹ wàá ni t'ìrèké. 

Síwájú sí í lo tún gbàdúrà pe

Òní l'àyájọ́ òmìnira 
Kí òmìnira má ṣe di omi ìnira fún wa 
K'ára má ṣe ni wá 
Ká a má ṣe rí ìnira 
Ká a má ṣe rí ìnira nílé 
Ká a má ṣe rí ìnira lọ́nà 
Kí ìgbà ó dẹ̀ wá 
Bí igbà ṣe n dẹ kòkó l'ágbàlá

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI