Lati di gbajumọ tabi gbajugbaja ki i ṣe iṣẹ ọjọ kan ṣoṣo, ati pe ojoojumọ l'awọn eeyan kaakiri agbaye n ronu ọna lati fi itan tuntun balẹ, eyi ti yoo tun ṣe awọn eeyan ni kayeefi bi wọn ba gbọ.
Ohun to daju ni pe b'awọn kan ṣe n f'itan tuntun fun iwe akọsilẹ agbaye, iyẹn Guiness book of Record balẹ, to si maa n jẹ iwuri, bẹẹ l'awọn mi in naa n f'itan ti wọn balẹ to si maa n jẹ kayeefi ati iyalẹnu nla.
L'ọdun diẹ sẹyin ni obinrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Lisa Sparks f'itan manigbagbe balẹ lagbaye, itan naa ko si le parẹ titi lai, ayafi bi ẹnikan ba tun dide lati ṣe ju tiẹ lọ.
Itan tuntun ti Lisa Spark fi balẹ ni ti ẹẹdẹgbẹrun-le-ni-mọkandinlogun (919) ọkunrin to ba a laṣepọ.
No comments:
Post a Comment