Ẹ WOJU AYALEGBE TO GUN BABA ONILE RẸ PA NITORI OBINRIN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, October 8, 2020

Ẹ WOJU AYALEGBE TO GUN BABA ONILE RẸ PA NITORI OBINRIN


Bo tilẹ jẹ pe a ko ti i gbọ kulẹkulẹ bi ayalegbe kan, Oneamachi Mmaju, ọmọ ọdun mọkanlelogun ṣe gun baba onile to gba ile lọwọ rẹ pa, ṣugbọn sibẹ, epe l'awọn eeyan n gbe ọdọmọkunrin naa ṣẹ titi ta a fi pari iroyin yii.

Kayeefi n'iṣẹlẹ naa ṣi n jẹ fun gbogbo awọn ara Ogidi Ani-Etiti to wa n'ijọba ibilẹ Idemili, ipinlẹ Anambra t'iṣẹlẹ naa ti waye.

 

Wọn ni ṣa dede l'awọn eeyan ri baba agbalagba naa, Nonso Umeadi ninu agbara ẹjẹ, ti wọn si sare gbiyanju lati doola ẹmi rẹ, ṣugbọn ti ẹpa ko boro rara.

Gbajumọ ni Umeadi t'awọn eeyan tun n pe ni Okpole n'ilu naa ati agbegbe rẹ.

 

Lara iroyin to tẹ AWIKONKO leti jẹ ko ye wa pe ọpọ igba ni baba onile naa ti kilọ fun Mmaju pe ko dẹkun awọn ọrẹbinrin to n ko wa s'ile oun, eyi ni wọn ni ko tẹ Mmaju lọrun.

L'ọjọ iṣẹlẹ buruku yii, wọn ni ṣe ni Mmaju gba ọrọ naa s'odi, to si sare lọ fa ọbẹ yọ, to fi gun baba naa pa. Ibi ti Mmaju ti fẹẹ na papa bora lọwọ ti tẹ ẹ, ti wọn si lọ fa a le awọn ọlọpaa lọwọ. 


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI