EKO, OGUN, KWARA L'AWỌN ILU TO N ṢE AṢEYỌRI - FDC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, October 8, 2020

EKO, OGUN, KWARA L'AWỌN ILU TO N ṢE AṢEYỌRI - FDC


Alakoko ileeṣẹ eto iṣuna kan ti wọn pe ni Financial Derivatives Company Limited (FDC), Ọgbẹni Bismarck Rewane ti fi orukọ ipinlẹ mẹsan an ti wọn n ṣe aṣyọri daadaa lasiko yii sita, to si ni ipinlẹ Kwara, Ọyọ, Ọṣun, Ekiti, Ogun, Ondo, Ẹdọ, Lagos ati Anambra.


Rewane lo ṣalaye eyi ninu iwe to kọ, eyi to pe ni “NIGERIA: Resource Rich & Cash Poor; Plenty Potential …Little Actual,”, eyi to fi n ṣayẹyẹ ayajọ ọgọta ọdun ti Naijiria ṣẹṣẹ pe laipẹ yii.

Ninu iwe naa lo tun ti ṣo pe awọn ipinlẹ mejila ni wọn bọ si agbegbe to jẹ pe aditu nla ni ọrọ wọn jẹ, to si ni awọn ipinlẹ naa ni Yobe, Borno, Jigawa, Kano, Bauchi, Gombe, Plateau, Adamawa, Taraba, Sokoto, Zamfara ati Niger.

Awọn ipinlẹ mẹẹdogun yooku to pe ni Katsina, Kẹbbi, Kaduna, FCT, Nasarawa, Kogi, Benue, Ẹnugu, Dẹlta, Imo, Akwa Ibom, Bayelsa, Rivers ati Ebonyi ni ọrọ wọn ṣi n fẹ adura ki wọn ba a le ṣe daadaa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI