#ENDSARS: Ẹ WOJU ỌMỌ ỌDÚN MỌKANLA TI WỌ́N FẸẸ JU S'Ẹ́WỌ̀N L'ẸDO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, October 30, 2020

#ENDSARS: Ẹ WOJU ỌMỌ ỌDÚN MỌKANLA TI WỌ́N FẸẸ JU S'Ẹ́WỌ̀N L'ẸDO


'Ẹni ṣango bá tojú rẹ wọlẹ̀, kò ní bá wọn bù ọba kòso' ni yóò jẹ fún ọmọdé kùnrin tí ẹ ń wo yìí, ẹni tó ń pè ara rẹ ní ọga àgbà pátápátá fáwọn ọlọpaa lorilẹ-ede Nàìjíríà tó bá fi lè bọ nínú wàhálà afọwọfa náà. 

Ọmọ náà ni wọn loo wọ aṣọ ọlọpaa nínú fọ́nrán kan tó gùn orí ayélujára laipẹ yìí, níbi táwọn èèyàn ti ń gbé òṣùbà fún un, tí wọn sì ń kì í ní mẹ́sàn-án mẹ́wàá. 

A tiẹ̀ tún gbọ pé ọmọ yìí tí wọn ní ọmọ ọdún mọ́kànlá ni báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọga ọlọpaa, tó sì mú káwọn èèyàn patẹwọ fún ún. 

Teṣan ọlọpaa tí Ọja Ọba tó wà n'ipinlẹ Ẹdo ni ọmọ yìí àtàwọn èèyàn rẹ tí ṣe fọ́nrán náà, tó sì káàkiri orí ayélujára. 

AWIKONKO gbọ pé ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ẹdo tí sọ pé àwọn yóò fojú rẹ bá ilé ẹjọ àwọn ọmọdé láti jẹ kò lọ kẹ́kọ̀ọ́ síwájú sí í. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI