#ENDSARS: GÓMÌNÀ SANWO-OLU KÉDE Ẹ̀KỌ́ Ọ̀FẸ́ FÁWỌN ỌMỌ ỌLỌPAA TO KU LÁSÌKÒ ÌFẸ̀HÓNÚHÀN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, October 29, 2020

#ENDSARS: GÓMÌNÀ SANWO-OLU KÉDE Ẹ̀KỌ́ Ọ̀FẸ́ FÁWỌN ỌMỌ ỌLỌPAA TO KU LÁSÌKÒ ÌFẸ̀HÓNÚHÀN


Gómìnà ìpińlẹ̀ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti pàsẹ fáwọn ilé tó ń ṣètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ní ìpińlẹ̀ Eko láti fún ọmọ àwọn ọlọ́pàá tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ abájádè ìfẹ́hónú ọ̀rọ̀ EndSars rìn.

Bákan náà ni Sanwo-Olu tún ni gbogbo ẹbí wọ́n ni yóò gba owó ìrànwọ́.

Gómìnà tún kéde pé, ètò wà nílẹ̀ láti tún gbogbo àwọn àgọ́ ọlọ́pàá tí wọn ti dáná sun, tí wọn yóò sì ra ọkọ̀ míràn tí àwọn jàndùkú ti bàjẹ́.

Babajide ṣe àwọn ìlérí yìí lásìkò to sàbẹ̀wò sí olú ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìlú Ikeja láti báwọn sọ̀rọ̀ ìwúrí.

Àtẹ̀jáde kan fi yéni pé, ó kéré tàn àgọ́ ọlọ́pàá mọ́kàndílọ́gbọ̀n ní wọ́n sùn níná, ti àwọn ibùdó ọlọ́pàá kéékèké mẹ́tàdínlógún sì lọ síi pẹ̀lú.

O ní ojúṣe ko ṣee fọ́wọ́yẹpẹrẹ nu láwùjọ nítorí ìwà ìbàjẹ́ àwọn kan láàrín ọlọ́pàá, àti pé àìsí ọlọ́pàá láàrín ìlú lẹnú ọjọ́ mẹ́tà jẹ́ ǹkan ti ó kan gbogbo ará ìlú.

"Kọmísọ́nà ọlọ́pàá tí fí ìwé ẹ̀dùn ọlọ́pàá ṣọwọ́ sí ìjọba, àtàwọn ǹkan ti yóò mú ìwúrí bá àwọn ọlọ́pàá lásìkò yiì.

"Lẹ́yìn gbogbo làásìgbò tó wáyé lọ́sẹ̀ tó kọjá. Èmi gẹ́gẹ́ bíi gómìnà mo gba gbogbo ọ̀rọ̀ náà gẹ́gẹ́ bi ẹ̀bi mi, pàápàá jùlọ àwọn ǹkan alò ti kò tó, láti ọjọ́bọ, ọjọ́ kọkàndílọ́gbọ̀n, oṣù kẹwàá, gbogbo àwọn ǹkan ti ó wà nínú ìwé ẹbẹ̀ yìí ni àó máa gbé ìgbésẹ̀ lórí ẹ"

"Pàtàkì jùlọ nínú àwọn ìwé ẹ̀bẹ̀ ọlọ́pàá ní fífún àwọn ọmọ ọlọ́pàá tó d'olóògbé ni ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́, mo si ti dári àjọ tó n mójú tó ètò ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ nípìnlẹ̀ Eko láti fún gbogbo àwọn ọmọ wọ́n ni ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́.

Gẹ́gẹ́ bi Sanwo-Olu ṣe sọ gbogbo ọlọ́pàá tó bá ń ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ Eko yóò ni ètò adójútòfò ẹ̀mí (Life Insurance).

Bákan náà lo fi kun un pé, òun yóò pèsè ẹ̀rọ amúná wá 150kva fún àwọn ọlọpàá àti pé ìjọba yóò sowọ́n pọ mọ́ ilé iṣẹ́ mọ̀nàmọ́nà aládani, tí wọn yóò fi máa ní iná ni gbogbo ìgbà ìgbà.

Lati: BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI