AYẸYẸ ỌJỌ́ ÌBÍ ỌMỌ OGÚN ỌDÚN DÁ ÀRÍYÀNJIYÀN SÍLẸ̀ LORI AYÉLUJÁRA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, October 28, 2020

AYẸYẸ ỌJỌ́ ÌBÍ ỌMỌ OGÚN ỌDÚN DÁ ÀRÍYÀNJIYÀN SÍLẸ̀ LORI AYÉLUJÁRA


Laipẹ yìí ni ọmọbìnrin arẹwà kan ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ogún ọdún, tó sì gbé e sórí ìkànnì ayélujára ti agbẹyẹfo, ìyẹn Twitter pẹ̀lú oríṣiríṣi àkàrà òyìnbó táwọn èèyàn fi tà á lọrẹ. 

Àkàrà òyìnbó tí ọmọbìnrin tó pe ara rẹ̀ ní Ifedioku Klara yìí fi yà fọto ni kò dín ni marundinlọgbọn, tó sì lòun dúpẹ́ pé Ọlọ́run dá ẹmi òun si.

Báwọn kan ṣe ń kí kú oriire, bẹ́ẹ̀ làwọn èèyàn ń sọ̀rọ̀ loriṣiriṣi nípa ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ náà, táwọn kan sì ń sọ pé àwọn olólùfẹ́ rẹ lọkunrin ni wọn tá a lọrẹ. 

Èyí ni ohun tó kọ sórí fọto rẹ tó gbé síta náà:
Ohun táwọn kan ń sọ ní pe o ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn tó ń dáná abẹ fún un ní wón fi àwọn àkàrà òyìnbó tá a lọrẹ, tó fi pọ tó bẹ́ẹ̀, táwọn kan sì ń sọ pé kò sí ohun tó burú nibẹ. 


Díẹ̀ rèé lára ohun táwọn èèyàn ń sọ. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI