#ENDSARS: KO SẸNI TO KU NIBI IKỌLU LEKKI - SANWO-OLU PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, October 21, 2020

#ENDSARS: KO SẸNI TO KU NIBI IKỌLU LEKKI - SANWO-OLU PARIWO SITA


Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti sọ pe ko si ẹnikankan to ku nibi ikọlu awọn ọmọ ogun orilẹ-ede Naijiria s'awọn olufẹhonu han lodi si awọn ọlọpaa SARS ati SWAT ti wọn tun ṣẹṣẹ gbe kalẹ.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ, wọn ni nnkan bi aago meje kọja iṣẹju diẹ l'awọn ọmọ ogun orilẹ-ede yii yawọ too-geeti Lẹkki, ti wọn si ṣina ibọn bolẹ f'awọn to n fẹhonu han s'awọn ijọba, ti wọn ni b'awọn ọmọ ogun yii ṣe n p'awọn eeyan ni wọn n gbe oku pamọ, ti wọn ko si jẹ ki ẹnikẹni ri awọn oku ti wọn pa, nibi ti ogunlọgọ awọn eeyan ti farapa yannayanna.

Lonii ni Gomina Sanwo-Olu sọ pe ko sẹni kankan to ku nibi ikọlu naa, ati pe awọn meji ti wọn farapa kọja sisọ ni wọn ti n gba itọju lọwọ, to si ni ijọba ti n wa ọna abayọ si ohun t'awọn araalu n fẹ.

Sanwo-Olu to loun ko mọ nnkankan nipa b'awọn ṣọja ṣe lọ kọlu awọn olufẹhonu han ni oun ti n b'awọn alaṣẹ ileeṣẹ ologun sọrọ lati mọ nnkan to ṣẹlẹ ti wọn fi lọọ kọlu awọn eeyan naa lalẹ ana.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI