NNKAN DÉ! ÌGBÉSẸ̀ LÁTI RỌ ỌBA OLÚGBÉNLÉ L'ÓYÈ BẸ̀RẸ̀, WỌ́N L'AWỌN ARÁÀLÚ Ń BÍNÚ GIDI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, October 20, 2020

NNKAN DÉ! ÌGBÉSẸ̀ LÁTI RỌ ỌBA OLÚGBÉNLÉ L'ÓYÈ BẸ̀RẸ̀, WỌ́N L'AWỌN ARÁÀLÚ Ń BÍNÚ GIDI


Bí ìròyìn tó tẹ AWIKONKO lọ́wọ́ laipẹ yìí bá fi jẹ òtítọ́, afaimọ ni kí wọn má padà rọ Ọba Gbadewọle Kẹhinde  Olugbenle, Olú Ilaro lóyè lórí bí wọn ṣe fẹ̀sùn kan án wí pé ṣe ló ń gbabọdi lórí ìdàgbàsókè ìlú Ilaro.

Ilaro tó wà n'ijọba ìbílẹ̀ Yewa South, ipinlẹ Ogun la gbọ̀ pé ọjà kan tí wọn pé ni Ọja Igbó Ajé lo dá wàhálà ńlá silẹ láàárín Ọba Olugbenle àtàwọn kan, èyí tí wọn ni inu awọn aráàlú kò dùn sí í. 

Láti nǹkan bí ogún ọdún sì ọdún marundinlọgbọn sẹ́yìn là gbọ pé wọ́n ti ti ọjà náà pa látàrí bí wọn ṣe ló ó jóná, tí wọn sì làwọn ọlọja kò tá ọjà nibẹ mọ.

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ, AWIKONKO gbọ pé látìgbà tí Ọba Agunloye kinni, ìyẹn Ọba Olugbenle tí de ori ipò ni nnkan bí ọdún mẹ́sàn-án sẹ́yìn ni kò ti ronú nípa ìdàgbàsókè ọjà Igbó Ajé yìí. 

Wọ́n ni nǹkan bí oṣù méje sì mẹ́jọ sẹ́yìn ni ọkùnrin kan tí wọn pé orúkọ rẹ ni Hammed Ojuọlape, ẹni tí wọn lo yan iṣẹ àwọn tó ń mú ìdàgbàsókè bá ìlú, ìyẹn Developer láàyò láti tún ọjà náà kọ. 

Nígbà tí wọn ní Ojuọlape dìde láti ronú ona ti yòò gba láti jẹ ki ọjà náà padà sí bo ṣe wá tẹ́lẹ̀, wọn loo fi ọ̀rọ̀ náà lọ àwọn àgbààgbà kan láàárín ìlú, tí wọn sì ṣàlàyé bí yóò ti rín ín fún un. 

Wọn ní lẹ́yìn tó parí ìwádìí rẹ tán lo lọọ bá igbá-kejì alága ìjọba ìbílẹ̀ Yewa South, ìyẹn Ọnọrebu Salakọ, ẹni tí wọn loo ṣe atọ́nà bí Ojuọlape ṣe de ọdọ alága ìjọba ìbílẹ̀ náà, Ọnọrebu Ọlabọde Adegbenro; akọ̀wé, Ọnọrebu Haruna Dada Ayedogbon; alakoso eto ijọba ibilẹ (HOLGA), Arábìnrin Ayọrinde ati Onimọ-ẹrọ Adeyẹmọ.

Awọn wọnyii si ni wọn ṣeto bi Ọgbẹni Ojuọlape ṣe gba iwe aṣẹ lọwọ ijọba ibilẹ Yewa South, nitori bi wọn ṣe jẹ alakoso nibẹ, ti wọn si ni wọn fi ọkan rẹ balẹ wi pe awọn yoo ran an lọwọ digba ti iṣẹ yoo fi pari.
 
Fún bí oṣù kan ààbọ̀ sí méjì là gbọ pé wọn fi tó ìwé ki ọjà náà lè di àtúnṣe láti ọwọ Ọgbẹni Ojuọlape n'ijọba ìbílẹ̀ náà, tá a sì gbọ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ mílíọ̀nù ni wọn gba lọ́wọ́ ẹ nibẹ lati fi to iwe. 

Lẹ́yìn èyí làwọn kan tún sọ fún ọkùnrin náà pé afi kò tún tẹsiwaju láti lọ gba ìwé àṣẹ lọ́wọ́ ìjọba ipinlẹ Ogun lábẹ́ Gómìnà Dapọ Abiọdun.

Awọn alakose ijọba ibilẹ Yewa South yii la gbọ pe wọn gbe Ọgbẹni Ojuọlape, ọmọ bíbí ìlú Màdògà n'ijọba ìbílẹ̀ Ipokia lẹyin lọ si ọdọ ijọba ipinlẹ ogun to wa ni Oke-Mọsan nilu Abẹokuta lọ́dọ̀ àwọn tí ọ̀rọ̀ kan láti bù ọwọ lu àtúnṣe ọjà náà fún Ojuọlape. 

Fún bí oṣù márùn-ún là gbọ pé wọn fi tó ìwé náà lọ́dọ̀ kọmiṣanna fún eto òye jíjẹ àti ìdàgbàsókè ijọba ibilẹ, Ọnọrebu Afọlabi Afuapẹ àti ileeṣẹ to n ri sọrọ ètò àyíká àti ilẹ̀ {Urban and Lands} n'ipinlẹ Ogun.
 
AWIKONKO gbọ pe lẹyin ti wọn ṣe eyi tan ni Ọgbẹni Ojuọlape gba ọdọ Iyalọja ilu Ilaro, Alaaja Bọla Idowu lọ lati lọ fi to o leti wi pe oun ti gba aṣẹ lati ọdọ ijọba ipinlẹ Ogun pẹlu ijọba ibilẹ Yewa South lati tun ọja Igbo Aje ṣe, ti wọn si ni inu Iyalọja naa dun kọja sisọ.
 
Nibi ipade ti wọn ni Ojuọlape ṣe pẹlu Iyalọja ni wọn ni mama naa ti gba a nimọran wi pe ko yọju si Ọba Alaye ilẹ Yewa, Ọba Gbadewọle Kẹhinde Olugbenle lati fi to o lati, ati pe oun funra oun (Iyalọja) yoo tun ba a de ọdọ Kabiyesi lati fi to o leti.

Ọjọ naa naa la gbọ pe Alaaja Bọla Idowu de ile Kabiyesi lati ṣalaye nnkan to n ṣẹlẹ fun un, ti wọn si ni inu Ọba Olugbenle ko dun si i, ṣugbọn ti wọn ni ko gbe e soju.

A gbọ pe ohun ti Kabiyesi Olugbenle sọ ni pe ki ọkunrin naa yọju s'oun lati jọ sọrọ, ti wọn si ni lẹsẹkẹsẹ ni Iyalọja naa ti pe Ojuọlape lati tete yọju si Kabiyesi.

Eyi ni wọn lo o mu ki ọkunrin naa gbera lati lọ, ṣugbọn iyalẹnu ni wọn lo o jẹ nigba to debẹ, ti wọn ni Kabiyesi ko si nile, to si pe Iyalọja, koda ti wọn ni Iyalọja naa sọ pe otitọ ni, ṣugbọn ko pada lọ.
 
Ọjọ Ẹti-Fraide ọsẹ mẹrin sẹyin ni wọn sọ pe Ojuọlape pe Iyalọja wi pe oun yoo de Aafin Kabiyesi lọjọ Aje-Mọnde lati ṣalaye fun un, ṣugbọn ti wọn lo o jẹ Iyalẹnu pe nigba ti yoo fi di ọjọ Aiku-Sande, iyẹn lọjọ to ku ọla ki ọkunrin naa yọju si Kabiyesi la gbọ pe Ọba Olugbenle paṣẹ pe ki awọn oloro lọọ ta mariwo yika ọja naa, wipe ẹnikẹni ko gbọdọ wọbẹ ṣe ohunkohun.
 
Eyi si ni wọn lo o bi awọn ọmọ ilu ninu wi pe asiko ti idagbasoke fẹ maa wọ ilu Ilaro wa ni Ọba Olugbenle paṣẹ pe ko le ṣeeṣe, ti wọn si ni iru nnkan bayii ki i ṣe akọkọ.

Wọn ni ohun ti Ọba Olugbenle n pariwo kaakiri bayii ni pe ẹni to fẹ wa a tun ọja Igbo Aje ṣe ki i ṣe ọmọ bibi ilu Ilaro, ko si leto lati ṣe iru nnkan bẹẹ, ṣugbọn ti wọn láwọn araalu n sọ fun Kabiyesi wi pe oun ni olori Ọba Yewa, ki i ṣe Ilaro nikan lo jẹ ọba si, ati pe Ojuọlape ti wọn n sọ yii, ọmọ ilẹ Yewa loun naa.

Ana la gbọ pe awọn araalu ti ọrọ naa ko dun mọ ninu pinu lati fẹhonu itagbangba han si igbesẹ kabiyesi yii, ṣugbọn ti wọn ni ifẹhonu han ti #ENDSARS to n lọ lọwọ ni ko jẹ ki wọn ṣe e.

N'igba to n b'AWIKONKO sọrọ laaarọ ana ti i ṣe Mọnde, Alaaja Bọla Idowu sọ pe "Awuyewuye to wa ko ju pe aigbora-ẹni-ye lọ. Difẹlọpa (Developer) lo wa a ba mi laipẹ yii pe oun fẹẹ kọ ọja Igbo Aje.

"Igbakeji alaga ijọba ibilẹ, Ọnọrebu Salakọ; akọwe ijọba ibilẹ,Ọnọrebu Dada Ayedọgbọn at'awọn mi in ni wọn jọ wa. Inu mi dun gan pẹlu igbesẹ yii. O si jẹ ko ye mi pe ijọba ipinlẹ Ogun ti fun oun ni aṣẹ lati kọ ọja naa.

"Ọja yii ti le ni ogun ọdun ti a ti tii pa nitori ina to jo o. Ẹgbẹẹgbẹ ọja yii l'awọn eeyan ti n taja. L'ọjọ naa ni mọ tun sọ fun un pe ko lọ ri Ọba Olugbenle nitori pe ọba lo ni ilu. Emi ko ni agbara lati paṣẹ pe ko tẹsiwaju ọja naa.

"Ọjọ keji to wa ba a mi ni mo de ọdọ Kabiyesi lati ṣalaye fun wọn, Kabiyesi ni awọn yoo maa reti ẹ. Ni ọjọ ti mo tun pada lọ s'ọdọ Kabiyesi, mo ni ṣe ọkunrin difẹlọpa naa ti wa, kabiyesi l'awọn ko ri i. Mo si tun pe Ojuọlape pe ko tete yọju si kabiyesi nitori pe ọba lo ni aṣẹ lọwọ.

"Ọjọ Fraide ni ọjọ yẹn, o wa sọ fun mi pe oun maa lọ ri Kabiyesi lọjọ Mọnde to tẹle, ṣugbọn ṣe ni nnkan yi pada nigba to maa fi di ọjọ Sande. Ojuọlape ko ti i ri ọba ti a ti n gbọ pe awọn eeyan ti n gba fọọmu lati fi gba ṣọọbu. Aarọ ọjọ yẹn ni mo n gbọ pe Oro ti lọ ta mariwo yika ọja.

"Iyalẹnu lo jẹ fun mi, mo si dide lọ sile ọba, mi o ri Kabiyesi, mi o si ri ẹnikẹni ba sọrọ, igba ti mo de ọdọ awọn Oloro, ni wọn sọ pe ilu lo gbe igbesẹ. Aarin ọjọ mẹrin sira wọn ni ọrọ yii fi ṣẹlẹ to fi di pe wọn n ta mariwo yika ọja."

Bolaji Leigh

Read more at: https://www.vanguardngr.com/2015/03/im-not-in-jonathans-campaign-team-olu-of-ilaro/
"Amọran mi si difẹlọpa yii ni pe ko lọ yanju ọrọ ara rẹ pẹlu Kabiyesi, ki wọn jọ sọ asọyepọ, ọrọ ti ko la ariwo lọ rara ni."
 
Ọkan lara awọn ọmọ ilu to b'AWIKONKO sọrọ lori iṣẹlẹ yii, ẹni ti ko fẹ ka darukọ oun sọ pe "Ọdun kẹsan an ree ti ọba Olugbenle ti wa lori ipo awọn baba nla rẹ, ṣugbọn ti ko ronu lati tun ọja naa ṣe."
 
Ẹni naa ni ko yẹ ki Kabiyesi to j'ọba le ori gbogbo ilẹ Yewa maa da ọrọ ẹlẹyamẹya silẹ laaarin ilu, nitori pe ẹni ti wọn n sọ yii, ọmọ Yewa ni, ṣugbọn to ni Kabiyesi sọ pe ki i ṣe ọmọ Ilaro, ko si le ṣe nnkankan nibẹ.

AWIKONKO gbiyanju lati ba alaga ijọba ibilẹ Yewa South, Ọnọrebu Ọlabọde Adegbenro; igbakeji rẹ, Ọnọrebu Salakọ; akọwe ijọba ibilẹ, Ọnọrebu Haruna Ayedọgbọn, alakoso eto ijọba ibilẹ ati Onimọ-ẹrọ Adeyẹmọ sọrọ, ṣugbọn ti gbogbo wọn sọ pe awọn ko lọrọ lati sọ.

Ọnọrebu Salakọ ni ọrọ tiẹ jẹ ko ye wa pe ọrọ naa ti wa niwaju Ọnọrebu Afọlabi Afuapẹ to jẹ kọmiṣanna fun eto ijọba ibilẹ ati oye jijẹ, abẹnugọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, Ọnọrebu Oluọmọ at'awọn kan, to si ni oni ni wọn fẹẹ ṣe ipade lori ẹ.

Ọgbẹni Hammed Ojuọlape ninu ọrọ rẹ to ba AWIKONKO sọ jẹ ko wa pe ko ti i to asiko t'oun yoo sọrọ ati pe igbesẹ ti n lọ labẹlẹ, to si ni ibi ti nnkan ba de duro l'oun yoo jẹ ka gbọ bi asiko ba to.
 
Nigba to n ba AWIKONKO sọrọ lori foonu n'irọlẹ ọjọ Aje Mọnde ana, Ọgbẹni Abọlaji Leigh to jẹ agbẹnusọ fun Ọba Olugbenle lori ọrọ iroyin sọ pe ọrọ naa ko kan Kabiyesi rara, ati pe bi a ba fẹẹ gbọ ohunkohun lori ẹ, ka wa awọn oloye ilu lọ lati ba wa sọrọ.
 
AWIKONKO gbọ pe ilu Ilaro ko fara rọ lasiko yii lori bi wọn l'awọn araalu n binu gidigidi wi pe Kabiyesi ko gba k'awọn oludagbasoke ilu ṣiṣẹ idagbasoke n'ilu naa, paapaa lasiko ti wọn nilo iru iranlọwọ bayii.
 
Bẹẹ ni wọn l'awọn kan n rawọ ẹbẹ si ijọba ipinlẹ Ogun labẹ iṣakoso Gomina Dapọ Abiọdun lati wa nnkan ṣe sọrọ yii. Bakan naa l'awọn kan n bu ẹnu atẹ awọn alakoso ijọba ibilẹ Yewa South lori bi wọn ṣe n yọwọ ara wọn sẹyin lẹyin ọpọlọpọ owo ti wọn ti gba lọwọ Ọgbẹni Ojuọlape, ti wọn ko wa ọna àbáyọ. 

Ariwo táwọn aráàlú ń pá lásìkò yìí ni pé àwọn n fẹ́ àtúnṣe lori igbesẹ ọba náà mọ, nítorí tí wọn ní ọrọ ẹlẹyamẹya lo fi ń darí ìlú. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI