#ENDSARS: O PARI, ÈYÍ NI BI WỌN ṢE JI Ọ̀PÁ ÀṢẸ ỌBA AKIOLU SALỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, October 21, 2020

#ENDSARS: O PARI, ÈYÍ NI BI WỌN ṢE JI Ọ̀PÁ ÀṢẸ ỌBA AKIOLU SALỌ


Ko ti i sẹni to le sọ pato ibi ti ifẹhonu han #ENDSARS to n lọ kaakiri orilẹ-ede Naijiria lọwọlọwọ bayii yoo ja si lori b'awọn tọọgi at'awọn olufẹhonu han ṣe n dana sun gbogbo ileeṣẹ at'awọn ile awọn gbajumọ oloṣelu ti wọn ni wọn n f'ara ni wọn.
 
Lonii l'awọn olufẹhonu han tun gba Aafin Ọba ilu Eko, iyẹn Ọba of Lagos, Ọba Rilwan Akiolu lọ, ti wọn si dana sun Aafin naa.
 
Ko to o di pe wọn dana sun  Aafin naa la gbọ pe awọn tọọgi kan ti yawọ inu Aafin, ti wọn si gbe Ọpa Aṣẹ kabiyesi salọ.
 
Fọnran kan to tẹ AWIKONKO lọwọ lo f'idi rẹ mulẹ, nibi ti a ti ri awọn ọdọ kan ti wọn n gbe ọpa aṣẹ naa salọ.
 
-0:23

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI