#ENDSARS/#ENDSWAT: ỌṢINBAJO RAWỌ ẸBẸ S'AWỌN ỌMỌ NÀÌJÍRÍÀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, October 18, 2020

#ENDSARS/#ENDSWAT: ỌṢINBAJO RAWỌ ẸBẸ S'AWỌN ỌMỌ NÀÌJÍRÍÀ


Igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria, Ọjọgbọn Yemi Osinabjo lo sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi sita to si tun wa loju opo Twitter rẹ.

Ọjọgbọn Osinbajo ni ''mo mọ pe ẹ n binu, o si yẹ bẹẹ. O ye mi yekeyeke bi ọpọ ọdọ orilẹede ni inu wọn ko dun.''

''Ọpọ lo ro pe a ti dakẹ ju lọri ọrọ to wa nilẹ wi pe igbesẹ ijọba kudiẹ kaato. Wọn jare wa,'' Osinbajo lo sọ bẹẹ.

Igbakeji Aarẹ ni ''ọgọọrọ ọmọ Naijiria ni awọn ọlọpaa ti fi iya jẹ lọna aitọ, eyi ko si bofin mu.''

''Ojuṣe wa ni lati daabo bo awọn ọdọ papaa julọ lọwọ awọn ti ijọba n sanwo fun un lati daabo bo wọn,'' Ọjọgbọn Osinbajo lo woye bẹẹ.

Osinbajo gbagbọ pe iwọde #EndSARS to n lọwọ kaakiri orilẹede Naijiria ju ọrọ awọn ọlọpaa to n dunkoko mawọn ọdọ lọ nikan.

Skip Twitter post, 1

End of Twitter post, 1

O ṣalaye pe ijọba ti n ṣe ipade pẹlu awọn tọrọ kan lati ojutu si ohun tawọn ọdọ to n ṣe iwọde n beere fun.

''Emi fun ra mi ni alaga ipade pẹlu awọn gomina ipinlẹ mẹrindinlọgbọn ati minisita olu ilu Naijiria, Abuja nibi ti a ti gbe igbimọ ti yoo ṣe iwadii iwa ika tawọn ọlọpaa #SARS ti hu.

Bakan naa ni igbakeji Aarẹ kẹdun pẹlu idile Jimoh Isiaq ti ibọn ọlọpaa pa niluu Ogbomoso atawọn mii naa to ti ba iwọde #EndSARS

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI