#ENDSARS: LÁÀÁRÍN WÁKÀTÍ MẸ́TA, AWỌN ỌMỌ NÀÌJÍRÍÀ DÁ MÍLÍỌ̀NÙ MẸRIN NÁÍRÀ FÚN JANE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, October 18, 2020

#ENDSARS: LÁÀÁRÍN WÁKÀTÍ MẸ́TA, AWỌN ỌMỌ NÀÌJÍRÍÀ DÁ MÍLÍỌ̀NÙ MẸRIN NÁÍRÀ FÚN JANE


Jane n bawọn ọdọ se iwọde ati owo iwọde
Yoruba bọ wọn ni bi Oluwa ba n se rere, a sọ pe o n se ibi.

Oniruuru itumọ ni iwọde awọn ọdọ to n lọ lọwọ lee ni fun ọpọ eeyan, bi awọn miran se ro pe ohun buburu ni, amọ ohun ayọ lo n jẹ fawọn eeyan miran.

Idi ni pe iwọde awọn ọdọ to n fẹhonu han, ti wọn si n beere fun fifi opin si isẹ awọn ọlọpaa SARS, ti mu iroyin ayọ ba ọdọbinrin kan, Jane to jẹ akanda ẹda.

Amọ ipenija ara yii ko da ọmọbinrin naa duro lati dara pọ mọ awọn akẹẹgbẹ rẹ ninu iwọde ti wọn n se.

Aarọ ọjọ isinmi si ni wọn gbe iroyin nipa iwa akinkanju Jane yii sori ayelujara, ẹni ti wọn ni ko nisẹ lọwọ lati ọdun 2013 nitori ipenija ara to ni.

Awọn ọdọ akẹẹgbẹ rẹ yii ni wọn ni ihuwasi Jane naa wu awọn lori, ti awọn si fẹ seto iranwọ owo fun.


Ọpọ ọdọ to ka ikede yii nipa ọmọbinrin akanda ẹda naa ni ori wọn wu, ti wọn si n da owo jọ si apo asunwọn ti wsn gbe kalẹ fun Jane.

Fun iyalẹnu, laarin wakati mẹta ti ikede ẹdawo ọhun de ori ayelujara, awọn ọdọ yii atawọn ọmọ Naijiria miran ti da owo to fẹ wọ miliọnu naira fun Jane.

Awọn ọdọ naa ni awọn fẹ ra ẹsẹ atọwọda fun ọmọbinrin naa, ko le e maa rin lai lo igi mọ.

Ọba oke nikan si lo lee sọ iye ti Jane yoo ri ko jọ ki ilẹ oni to su, eyi to n parọwa siwa pe ilẹ aanu Oluwa kii su.

Láti: BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI