GÓMÌNÀ OYETỌLA TU ÀṢÍRÍ AWỌN TỌỌGI TO FẸẸ PA A DANÙ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, October 18, 2020

GÓMÌNÀ OYETỌLA TU ÀṢÍRÍ AWỌN TỌỌGI TO FẸẸ PA A DANÙ


Gómìnà ipinlẹ Ọṣun, Adegboyega Oyetọla lónìí tí tú àṣírí àwọn tọọgi tó lọ dènà de e n'ilu Oṣogbo níbi iwọde ifẹhonu han #ENDSARS táwọn ọdọ ń ṣe kiri. 

A gbọ pé àwọn méjì ni wọn dagbere fàyè níbi ìkọlù náà tí wọn tí gbìyànjú láti pá Gómìnà Oyetọla danu, ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé orí lo kò ó yọ. 

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lónìí, Gómìnà Oyetọla ni àwọn tó wà a kọlu òun kì í ṣe àwọn ọdọ tó ń fẹhonu hàn rárá, nítorí pé àwọn ọdọ tó ń jà fún ẹtọ wọn jẹ ẹni tó ń tẹle òfin orílẹ̀ èdè yìí. 

Oyetọla ni àwọn tọọgi olóṣèlú ẹgbẹ́ alátakò òun ni wọn wá láti dènà de òun ni ìkòríta Ọlaiya tó wà n'ilu Oṣogbo, ipinlẹ náà. 

Bẹẹ lo sọ pé igbesẹ tí bẹ̀rẹ̀ láti mọ àwọn tó ṣiṣẹ́ burúkú náà, tí wọn yóò sì fi ojú winna òfin. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI