#ENDSARS: WÀHÁLÀ ŃLÁ DÉ BÁ ÀWỌN ỌLỌPAA N'IPINLẸ Ọ̀YỌ́ L'ORI IGBESẸ MAKINDE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, October 18, 2020

#ENDSARS: WÀHÁLÀ ŃLÁ DÉ BÁ ÀWỌN ỌLỌPAA N'IPINLẸ Ọ̀YỌ́ L'ORI IGBESẸ MAKINDE


Ìjọba ipinlẹ Ọ̀yọ́  ìṣàkóso Gómìnà Ṣeyi Makinde lónìí yí kéde síta wí pé òhun kò ní í fi ọwọ yẹpẹrẹ mú ọ̀rọ̀ àwọn ọlọpaa mọ, àti pé àwọn yóò bẹ̀rẹ̀ si í fi àwọn ọlọpaa j'ofin. 

Gómìnà Makinde nígbà tó ń kéde ọ̀rọ̀ náà síta lórí ìkànni ayélujára rẹ lónìí sọ pé àwọn tí gbé igbimọ kan kalẹ tí yóò máa rí sì báwọn ọlọpaa ṣe ń fìyà jẹ àwọn èèyàn lọ́nà tí kò bá òfin mú. 

Imeeli kan àti ìkànni ayélujára ni ijọba ipinlẹ Ọ̀yọ́ tí gbé kalẹ báyìí fáwọn aráàlú láti máa fi gbogbo ọ̀rọ̀ àwọn ọlọpaa tó ìjọba létí láti lè gbé ìgbésẹ̀ tó bá yẹ leè lórí. 

Imeeli náà ni:

Ìkànni ayélujára náà ni:

Nibẹ làwọn tó bá fẹẹ fi ẹjọ́ àwọn olopaa sún ìjọba, tí wọn yóò sì tún ṣàlàyé lẹkunrẹrẹ nínú fọọmu tí wọn gbé síta. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI