LẸ́YÌN OṢÙ MÁRÙN-ÚN, GBAJÚMỌ̀ SỌ̀RỌ̀SỌ̀RỌ̀ FẸẸ ṢAYẸYẸ OGÚN ỌDÚN LÓRÍ AFẸ́FẸ́ N'ILU ABẸ́ÒKÚTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, October 8, 2020

LẸ́YÌN OṢÙ MÁRÙN-ÚN, GBAJÚMỌ̀ SỌ̀RỌ̀SỌ̀RỌ̀ FẸẸ ṢAYẸYẸ OGÚN ỌDÚN LÓRÍ AFẸ́FẸ́ N'ILU ABẸ́ÒKÚTA


Púpọ̀ àwọn olólùfẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ orí rédíò àti telifiṣan nnì, Kọmureedi Akinyẹmi Ọlatoye tí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn mọ sì Alawiye Fẹdireṣan ni wọn ti ń béèrè pé ìgbà wo ni ayẹyẹ ogún ọdún rẹ lórí afẹ́fẹ́ yóò wáyé, ṣùgbọ́n tí wọn sùúrù lo ń sọ fún wọn pé kí wọn lọ ní.

Oṣù kẹta sì oṣù kẹrin ọdún yìí ni Alawiye Fẹdireṣan fẹẹ ṣe ayẹyẹ onibẹta ńlá náà, ṣùgbọ́n tí ajakalẹ àrùn koronafairọọsi, ìyẹn Covid-19 kò jẹ kò ṣeé ṣe lásìkò látàrí òfin konilegbele tó wà níta.

Alawiye là gbọ pé ó ti mú aṣọ nígbà náà táwọn olólùfẹ́ rẹ yóò wọ wá síbi ayẹyẹ náà, níbi tó fẹẹ ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún marundinlogoji, ayẹyẹ ogún ọdún nìdí iṣẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ àti akojọpọ àwọn ètò rẹ, ìyẹn Láwùjọ Akọni tó ṣe sínú kasẹẹti.

Ní báyìí, gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ, wọn ní ayẹyẹ náà yóò padà wáyé lọ́jọ́ kẹfà oṣù kọkànlá ọdún yìí. 

AWIKONKO gbọ́ pé gbọngan ayẹyẹ tí ONTEC tó wà lẹgbẹ ileeṣẹ rédíò Splash FM, Abiọla-Way n'ilu Abẹ́òkúta ni ayẹyẹ náà yóò ti waye bẹ̀rẹ̀ láti aago méjìlá ọ̀sán. 


Gẹ́gẹ́ àwọn tó fi ìròyìn náà tó AWIKONKO lọ́wọ́ ṣe sọ, wọn ní aṣọ ẹbí àti tikẹẹti 'Raffle Draw' làwọn èèyàn yóò fi wọlé sí gbọngan ayẹyẹ lọ́jọ́ naa, ti wọn si lọ́jọ́ náà máa larinrin kọjá sísọ.

Àwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn ni wọn máa peju síbẹ̀ lọ́jọ́ náà. Ẹni tó bá sì debẹ ni yóò ròyìn. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI