ỌFFA METRO CLUB ṢE BẸBẸ, IWURI NLA L'OHUN TI WỌN ṢE YII - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, October 7, 2020

ỌFFA METRO CLUB ṢE BẸBẸ, IWURI NLA L'OHUN TI WỌN ṢE YIIPẹlu igbesẹ ti ẹgbẹ kan ti wọn pe ni Ọffa Metro Club gbe laipẹ yii, o fi han daju wi pe wọn fẹran araalu, wọn si n wa alaafia awọn araalu, iyẹn n'ipinlẹ Kwara.
 
Ohun iwuri ni wọn ṣe nipa kikọ ibudọ iṣẹlẹ ijamba ati iṣẹlẹ pajawiri, iyẹn Accident and Emergency Unit s'ijọba ibilẹ Ọffa, ipinlẹ Kwara.
 
Gomina AbdulRahman AbdulRazaq t'ipinlẹ naa ti wa a gbe oṣuba kare fun wọn lori igbesẹ naa, to si lu wọn lọgọ ẹnu pe wọn ku iṣẹ takuntakun nipa riran ijọba lọwọ.

Aṣoju Gomina, Kọmiṣanna fun eto ilera, Dọkita Raji Razaq n'igba to n sọrọ nibi ifilọlẹ ibudo iṣẹlẹ pajawiri naa ti wọn kọ si ọsibitu ijọba to wa ni Ọffa, o ni ṣe ni wọn pe ijọba n'ija lati ṣe ju ohun ti wọn ṣe yii lọ.
 
Obitibiti owo to le ni miliọnu la gbọ pe wọn fi kọ ibudo yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI