ÀLÀBÍ ÌKỌ̀Ọ́, GBAJÚMỌ́ AKÉWÌ FẸẸ GBÉ KASẸẸTI TUNTUN JÁDE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 16, 2020

ÀLÀBÍ ÌKỌ̀Ọ́, GBAJÚMỌ́ AKÉWÌ FẸẸ GBÉ KASẸẸTI TUNTUN JÁDE


Gbogbo eto lo ti fẹẹ pari bayii fun ọkan lara awọn sọrọsọrọ to ṣẹṣẹ n dide bọ n'ipinlẹ Ogun, Abiọdun Alabi, ẹni t'ọpọ awọn eeyan mọ si Alabi Ikọọ lati gbe kasẹẹti tuntun to pe ni 'Kawe Kọ'ṣẹ' jade.

Ogunjọ oṣu kejila ọdun yii (December 20, 2020) ni ikojade awo orin naa yoo jade ninu gbọngan ayẹyẹ Banza Blue Roof Hotel to wa lagbegbe Olokodo, Okeserin nilu Igboọra, ipinlẹ Ogun bẹrẹ lati aago mọkanla aarọ.


Odu ni Alabi Ikọọ, t'awọn eeyan tun n pe ni Ọmọ Tapa Lempe, paapaa lori eto Owuye ti ileeṣẹ redio Fresh FM nilu Abẹokuta, t'awọn eeyan si fẹran lati maa gbọ awọn ewi rẹ ni gbogbo alẹ Ọjọru-Wẹsidee.

AWIKONKO gbọ pe kasẹẹti naa lo ṣe lati fi gb'awọn eeyan lamọran nipa ibi ti ile aye, paapaa orilẹ-ede Naijiria n dorikọ lasikọ yii nipa ọrọ iṣẹ, to si sọ nibẹ pe b'awọn eeyan ba ṣe n lọ sileewe, ki wọn tun gbiyanju lati maa kọ iṣẹ lẹgbẹ kan.

Eyi ni iwe-ipe s'ibi eto naa at'awọn ti yoo wa nibẹ:




No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI