O ṢEE ṢE KI WỌN YỌ GERNOT ROHR DANU L'ỌSẸ YII - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 16, 2020

O ṢEE ṢE KI WỌN YỌ GERNOT ROHR DANU L'ỌSẸ YII


Bi ikọ ẹgbẹ agbabọọlu orilẹ-ede Naijiria, iyẹn Super Eagles ko ba ta putu ninu ifẹsẹwọnsẹ to fẹẹ waye laaarin awọn ati ikọ ẹgbẹ agbabọọlu orilẹ-ede Sierra Leone lọjọ Iṣẹgun-Tusidee ọla, o ṣee ṣe ki wọn yọ akọnimọngba wọn, Gernot Rohr danu.
 
Minisita fọrọ ere idaraya lorilẹ-ede yii, Sunday Dare lo yan ọrọ yii sita wi pe ifẹsẹwọnsẹ t'awọn Super Eagles gba lọsẹ to kọja yii bani lọkan jẹ pupọ.
 
Ọjọ Iṣẹgun Tuside ọla ni Super Eagles yoo tun koju Sierra Leone lẹẹkeji. Ọọmi ayo mẹrin-mẹrin l'awọn mejeeji gba lọsẹ to kọja.
 
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Ohun to wa nilẹ bayii ni lati ri i pe awọn ẹgbẹ agbabọọlu yii yanrannti lati le ri tikẹẹti AFCON t'ọdun 2022 gba. Bi wọn ba bori ni Freetown ni yoo jẹ ka mọ boya a maa lọ si AFCON l'ọdun 2022.
 
"Lẹyin ifẹsẹwọnsẹ naa la ṣẹṣẹ maa mọ igbesẹ ti a fẹ gbe lori ọrọ akọnimọngba wa, Rohr boya yoo duro ni tabi ka lee danu, ki Super Eagles si le pada si ipo nla ti wọn wa tẹlẹ lagbaye."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI