AWỌN ARAALU TUN JẸ ANFAANI ETO AYẸWO ILERA ỌFẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, November 27, 2020

AWỌN ARAALU TUN JẸ ANFAANI ETO AYẸWO ILERA ỌFẸ


L'Ọjọbọ ti i ṣe Tọsidee ana l'awọn araalu Osi níjọba ibilẹ Ẹkiti ipinlẹ Kwara jẹ anafaani eto ayẹwo ilera ọfẹ t'ijọba ipinlẹ naa ṣagbatẹru ẹ.
 
Kaakiri ipinlẹ naa la gbọ pe eto ti wọn pe ni State-Wide Free Surgical Intervention naa ti n lọ.
 
A gbọ pe b'awọn eeyan ṣe n jẹ anfaani naa l'awọn to nilo itọju ati iṣẹ abẹ tun n gba a lọfẹ, t'awọn to ṣẹṣẹ bimọ naa tun n gba itọju.
 
Ẹgbẹ awọn dọkita ati eleto ilera ijọba ti wọn pe ni  National Association of Government General Medical and Dental Practitioners (NAGGMDP), ẹka t'ipinlẹ naa la gbọ pe o ṣagbatẹru eto yii lati fi ran awọn araalu lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI