EEDI RE O! BABA GE ỌMỌ BIBI INU Ẹ LORI DANU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, November 27, 2020

EEDI RE O! BABA GE ỌMỌ BIBI INU Ẹ LORI DANU


Ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Jigawa ti tẹ baale ile kan ọmọ ọgbọn ọdun kan, Alhassan Ya’u ti wọn lo o ge ọmọ bibi inu rẹ lori danu, tiyẹn si gbabẹ ku patapata.
 
Sani Alhassan, ti wọn lo o ṣẹṣẹ pe ọmọ ọdun kan ni ọmọ naa to ge lori.
 
Ọjọ Aje, Mọnde to kọja yii n'iṣẹlẹ naa waye labule Dankargo nijọba ibilẹ Jahun, ipinlẹ Jigawa.
 
AWIKONKO gbọ pe aarun ọpọlọ n da baba naa laamu tẹlẹ, ti wọn si ni ko sẹni ti ko mọ ni gbogbo abule naa.
 
Wọn ni ṣe ni Ya'u gbe ọmọ naa wọnu yara, to si ja ikọfun rẹ titi to fi ku, ko to fun fi ọbẹ gẹ ọrun ẹ danu.
 
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ naa, Abdu Jinjiri f'idi iṣẹlẹ naa mulẹ, to si ni nnkan bi aago mẹsan aarọ n'iṣẹlẹ naa waye, to si l'awọn ti fidi rẹ mulẹ pe loootọ ni aarun ọpọlọ n da baba naa laamu.
 
O wa lawọn ti gbe e lọ si ọsibitu nibi ti wọn ti n tọju awọn alaarun ọpọlọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI