Ẹ GBỌ NNKAN TI GOODLUCK JONATHAN SỌ FUN BIDEN LATI ṢE NINU IṢAKOSO RẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, November 8, 2020

Ẹ GBỌ NNKAN TI GOODLUCK JONATHAN SỌ FUN BIDEN LATI ṢE NINU IṢAKOSO RẸ

Aarẹ ana lorilẹ-ede Naijiria, Goodluck Ebele Jonathan ti ku Aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan nilẹ Amẹrika, Joe Biden ku oriire, to si loun lẹni t'awọn eeyan n fẹ, idi ree to fi loo jawe olubori ninu eto idibo to waye lọjọ kẹta ọsu yii.

Lonii ni Goodluck Jonathan gbe atẹjade kan sita, eyi to fi n gba Aarẹ ilẹ Amẹrika tuntun naa, Joe Biden lamọran lati ṣe nigba to ba de ori ipo naa.

Jonathan loun n'igbagbọ pe Biden yoo lo ipo rẹ lati gbogun ti arun koronafairọọsi, iyẹn Covid-19, ko si tun ṣiṣẹ lori alaafia agbaye ati aṣeyọri lẹyin ti ajakalẹ arun naa ba kasẹ nilẹ.

O ni ki i ṣe itan nikan ni bi Biden ati igbakeji rẹ, Harris ṣe jawe olubori fi lelẹ, bi ko ṣe pe o tun sọ nnkan ti ọjọ iwaju yoo jẹ pẹlu, ati pe ki i ṣe nipa ẹsin tabi ẹya bi ko ṣe nigba ọkan akikanju ati nnkan teeyan le ṣe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI