EYI L'AWỌN AṢIRI IKU TO PA GBAJUMỌ SỌRỌSỌRỌ AGBAYE NNI, ALEX - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, November 8, 2020

EYI L'AWỌN AṢIRI IKU TO PA GBAJUMỌ SỌRỌSỌRỌ AGBAYE NNI, ALEX


Gbogbo awọn ololufẹ ọkunrin naa ni wọn n banujẹ, ti wọn si n kanminu lori iku gbajugbaja ati ogbontarigi sọsọrọsọ agbaye nni, Alex Trebek to d'oloogbe lẹni ọgọrin ọdun.


Inu ile ẹ la gbọ pe ọkunrin naa ti dagbere f'aye lẹyin ọdun kan ati oṣu meloo kan ti aisan jẹjẹrẹ ti n ba a ja lagọ ara.

Aisan jẹjẹrẹ naa ti wọn pe ni Stage 4 Pancreatic Cancer ni wọn lo o kọlu Alex l'oṣu kẹta ọdun to kọja, ti wọn si loo ti na ọpọlọpọ owo lee lori lati le jẹ ko lọ, ṣugbọn ti aisan naa pada ran an lọ sọrun.

Odu ni Alex, ki i ṣaimọ f'oloko nidi iṣẹ sọrọsọrọ awọ alawọ funfun, oun si lo maa n tukọ gbajugbaja eto ti wọn pe ni Jeopardy.

Awọn alakoso eto Jeopardy ni wọn gbe iroyin iku ọkunrin naa sita lori ikanni ayelujarati Twitter wọn laipẹ yii, ti wọn si loo b'awọn lọkan jẹ pupọ.

A gbọ pe oṣu to kọja ni Alex wọ yara igbohunsilẹ lati ṣe awọn eto rẹ kalẹ, ta a si gbọ pe ọjọ ọdun keresimesi, iyẹn ọjọ karundinlọgbọn oṣu kejila ọdun yii ni eto to ṣe kalẹ yoo dopin lati ṣe awọn mi in, ṣugbọn ti ọlọjọ ti tete de.

Ọdun 1961 ni Alex bẹrẹ iṣẹ igbohunsafẹfẹ pẹlu ileeṣẹ Canadian Broadcasting Corporation, to si jẹ pe ko pẹ to fi lokiki lẹyin to bẹrẹ eto kan to pe ni “Reach for the Top.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI