EMI O NI BA WỌN WA IṢUBU TINUBU LAILAI - FAYOṢE TUN JU BỌMBU ỌRỌ SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, November 22, 2020

EMI O NI BA WỌN WA IṢUBU TINUBU LAILAI - FAYOṢE TUN JU BỌMBU ỌRỌ SITA

Gomina ana n'ipinlẹ Ekiti, Peter Ayọdele Fayoṣe ti sọ pe oun ko ni i ba wọn darapọ mọ ẹgbẹ awọn ọlọtẹ lati ba wọn wa iṣubu Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu lẹka eto oṣelu nitori pe ẹnikan ṣoṣo t'awọn n wo gẹgẹ bi aṣiwaju rere niyẹn.
 
O ṣapejuwe Tinubu gẹgẹ bi ọkan pataki lara awọn to n gbe ilẹ Yoruba larugẹ ni gbogbo ọna, paapaa orilẹ-ede Naijiria lapapọ.
 
Fayoṣe tẹsiwaju pe bo tilẹ jẹ pe oun ko si ninu ẹgbẹ oṣelu kan naa pẹlu Aṣiwaju Tinubu, sibẹ, o loun ko ni ikunsinu kankan pẹlu ẹ, to si ni ṣe lo yẹ k'awọn gbiyanju lati maa fi imọriri han s'awọn to ba ti ko ipa rere lawujọ lai wo ti ọrọ oṣelu ninu.
 
Ọjọ Abamẹta-Satide ana ni Fayoṣe sọrọ yii lasiko to n b'awọn oniroyin sọrọ fun ti ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọta ọdun ẹ. Nibẹ lo tun ti sọ pe ko si ija laaarin oun ati Gomina Ṣeyi Makinde t'ipinlẹ Ọyọ ati Biọdun Olujimi toun n ṣoju ẹkun Ekiti South nile igbimọ aṣofin Abuja, o ni nnkan to wa laarin wọn to o yanju ninu ẹgbẹ. 
 
Nibẹ lo tn ti sọ pe gbogbo awọn to n fo kaakiri ẹgbẹ oṣelu kan si ekeji lo jẹ pe ole ni wọn, ati pe atijẹ ni wọn n wa, nitori pe wọn ko ni nnkankan lọpọlọ ju nnkan ti wọn fẹẹ jẹ lọ. 
 
O tẹsiwaju pe pẹlu gbogbo wahala to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP lasiko yii, oun ko ni i fo kaakiri bi awọn agba oṣelu yooku.
 
“Bi a ba n ja ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, ẹ jẹ ka maa ba ara wa ja nibẹ. Awọn ole ni wọn n fo kaakiri, ati pe wọn ko mọ iwọn ara wọn ni, ọkanjuwa lo n ṣe wọn. 
 
“Awọn to n fo kaakiri ẹgbẹ oṣelu kan si ekeji ti jẹ ka mọ iru adari ti a ni lorilẹ-ede yii ti wọn ko ni oye tabi imọ. Nnkan ti wọn ro pe o le ṣe anfaani fun wọn ni wọn n ba lọ.
 
“Ipo oṣelu wa n ṣaisan. Gbogbo nnkan to wa ni Naijiria lo n ṣaisan, to si jẹ pe ojuṣe awọn aṣaaju wa si ni. Gomina Umahi’s to lọ darapọ mọ APC lẹyin ọpọlọpọ anfaani to ti jẹ ninu ẹgbẹ PDP ti fi ye wa pe ko ni ikora-ẹni n'ijanu. Awa ko le tẹwọ gba awijare rẹ lailai. 
 
“Inu mi ko dun si pupọ awọn nnkan to n ṣẹlẹ ninu PDP, ṣugbọn wi pe a wa n fi ẹgbẹ naa silẹ kọ ni ọna abayọ, bi ko ṣe ba wa iyanju si ẹ.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI