O MA ṢE O! ỌLỌPAA LU ỌMỌ OGUN ỌDUN PA L'OṢOGBO, L'AWỌN OṢIṢẸ ỌSIBITU KO BA TUN GBE OKU Ẹ SILẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, November 22, 2020

O MA ṢE O! ỌLỌPAA LU ỌMỌ OGUN ỌDUN PA L'OṢOGBO, L'AWỌN OṢIṢẸ ỌSIBITU KO BA TUN GBE OKU Ẹ SILẸ


Mọlẹbi kan ti wọn ni ọlọpaa kan lu ọmọ wọn, Ayọmide Taiwo, ọmọ ogun ọdun pa l'oṣu kẹjọ ọdun yii ni wọn ti n bẹbẹ fun iranlọwọ ijọba at'awọn araalu lori bi wọn ṣe l'awọn oṣiṣẹ ọsibitu to ku si ko ṣe gbe oku ẹ silẹ fun wọn lati sin.
 
Bẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹrin oṣu kẹjọ ọdun yii ni iroyin naa jade sita wi pe ọkan lara awọn ọlọpaa orilẹ-ede yii ti wọn ti le danu lẹnu iṣẹ fi idi ibọn fọ Ayọmide lori nitori ko fun un ni aadọta (N50) naira, owo riba, to si jẹ pe ọsibitu lo pada ku si lẹyin ọjọ kẹfa.
 
Ẹgbọn Ayọmide, Adebayọ Popoọla lo bẹ ijọba at'awọn araalu pe ki wọn ṣaanu wọn lati gba oku ọmọ naa jade, iyẹn bo ṣe sọ pe owo t'awọn oṣiṣẹ ọsibitu naa n beere kọja agbara wọn. 
 
Ọsibitu ti Ladoke Akintọla, iyẹn LAUTECH to wa nilu Oṣogbo la gbọ pe Ayọmide ku si ni nnkan bi aago mẹjọ aabọ aarọ ọjọ kẹsan-an oṣu kẹjọ ọdun yii, ori ẹsun yii si ni wọn fi le ọlọpaa naa danu. 
 
Iya Ayọmide, Yẹmisi Taiwo sọ pe awọn ti ta oko wọn, t'awọn si tun ti ya owo lati doola ẹmi ọmọ naa, ṣugbọn to jẹ pe pabo lo ja si f'awọn.
 
A gbọ pe ẹgbẹrun mọkandinlọgọrin (N79,000) naira l'awọn ọsibitu naa n beere ki wọn to le gba oku Ayọmide jade, ṣugbọn ti wọn lawọn eeyan naa ko ri san. Ẹgbẹrun mọkanla pere la gbọ pe wọn ri san ninu owo naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI