ETO AABO: TETE BEERE ỌNA ABAYỌ LỌWỌ FAYOṢE, PDP GBA FAYẸMI LAMỌRAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 30, 2020

ETO AABO: TETE BEERE ỌNA ABAYỌ LỌWỌ FAYOṢE, PDP GBA FAYẸMI LAMỌRAN


Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) n'ipinlẹ Ekiti ti gba gomina ipinlẹ naa, Kayọde Fayẹmi lamọran wi pe ko tete pe gomina ana, Ayọdele Fayoṣe lati beere ọna si eto aabo to mẹhẹ n'ipinlẹ naa ko to o pẹ ju.
 
Wọn ni ohun iyalẹnu ati kayeefi lo n jẹ wi pe ipinlẹ Ekiti to jẹ ipinlẹ ti alaafia ti n jọba tẹlẹ ti wa di ohun ti ijinigbe ati ipaniyan ti n ṣẹlẹ lojoojumọ, t'awọn tọọgi ijọbaa naa tun n dunkooko mọ awọn araalu.
 
Ẹgbẹ naa ni Gomina Kayọde Fayẹmi ranṣẹ pe ẹni to gba ipo lowọ ẹ, Ayọdele Fayoṣe lati beere awọn ọna to gba lati jẹ ki eto aabo ipinlẹ di ohun t'awọn ipinlẹ mi in fi n tọrọ.
 
A gbọ pe ijinigbe meji ọtọọtọ nibi t'awọn meji ti jade laye lo ṣẹlẹ l'ọsẹ to kọja yii laarin wakati mẹrinlelogun si ara wọn.
 
Ninu atẹjade ti ẹgbẹ naa fi sita, eyi ti agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Rapheal Adeyanju bu ọwọ lu ni wọn ti sọ pe eto aabo yẹ ko jẹ nnkan akọkọ ti yoo jẹ ijọba logun ninu eto iṣejọba to ba dara. 
 
Wọn ni ki Fayẹmi gbe ipinnu rẹ lati du ipo Aarẹ orilẹ-ede yii l'ọdun 2023 silẹ, ko si gbajumọ eyi to ṣe pataki si i, iyẹn eto aabo ipinlẹ Ekiti, k'awọn to fẹ wa s'ipinlẹ naa si le wa lai bẹru.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI