ARÁÀLÚ FARAYA TORÍ ÈÈYÀN ÀÁDỌ́FÀ TÓ DÈRÒ Ọ̀RUN NÍ BORNO, GÓMÌNÀ ZULUM KE GBAJARE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 30, 2020

ARÁÀLÚ FARAYA TORÍ ÈÈYÀN ÀÁDỌ́FÀ TÓ DÈRÒ Ọ̀RUN NÍ BORNO, GÓMÌNÀ ZULUM KE GBAJARE


O kere tan eeyan aadọfa lawọn ikọ aṣekupani Boko Haram ti ran lọ sọrun ọsangaan ninu ikọlu kan to waye ni ipinlẹ Borno.
 
 
Ṣaaju la gbọ pe eeyan mẹtalelogoji lo ba iṣẹlẹ naa lọ amọ bayii ti ajọ isọkanb agbaye ti toju bọ ọrọ naa wọn ni eeyan aadọfa lo ba iṣẹlẹ naa lọ. 
 
Ọrọ yi wa ninu atẹjade kan ti oludari eto iranwọ fawọn atipo ajọ naa, Edward Kallon fi sita lọjọ Aiku. 
 
Yatọ si awọn to ku yi, ọpọ lo farapa ninu ikọlu naa. 
 
Loju opo ayelujara, niṣe lawọn eeyan n gbarata ti ọpọ si n di ẹbi ru ijọba aarẹ Buhari fun pe ko mojuto eto aabo bo ti ṣe yẹ. 
 
Ninu ọr awọn eeyan , wọn ni ijọba ni la ti wa wọrọkọ fi ṣada lori ọrọ awọn agbesunmmi yi to jẹ pe ojujumọ lo n peleke si. 
 
Gómìnà Zulum bẹ Zabarmari, ìletò tí Boko Haram ti pa àgbẹ̀ 43 wò, Ó ní òkú tí wọ́n pa ṣì ju bẹ́ẹ̀ lọ̀ 
 
Wọn ti sin awọn agbẹ onirẹsi mẹtalelogoji tawọn agbebọn Boko Haram kọlu lọjọ Ẹti ti wọn si du loko ti wọn ti n ṣiṣẹ ọgbin wọn. 
 
Gomina ipinlẹ Borno, Ọjọgbọn Babangana Umara Zulum lo lewaju awọn olugbe ilu Zabarmari lowurọ ọjọ Aiku ti isinku naa waye lati sinku awọn agbẹ onirẹsi naa.  
 
Gomina Zulum ni ọrọ ti di adiyẹ ba lokun fawọn eeyan agbegbe naa nitori bi wọn joko sile ebi yoo pa wọn, bi wọn tun lọ siṣẹ loko bayii, awọn agbebọn Boko Haram lo tun n lọ ree pa wọn si oko iwa nkan jẹ. 
 
O ni lootọ olugbe ilu Zabarmari ni ijọba ibilẹ Jere lawọn eeyan ti wsn pa naa, amọṣa ileto Koshebe ni ijọba ibilẹ Mafa ni wọn ti da ẹmi wọn legbodo. 
 
Gomina Zulum ni lootọ oku eeyan mẹtalelogoji ni wọn sin lowurọ ọjọ Aiku, sibẹ ko tii si ẹni lee sọ ni pato iye awọn eeyan ti wọn pa. 
 
O fi kun un pe ọkan lara awọn olugbe ilu naa ti ko fẹ da orukọ ara rẹ ṣalaye fun oun lasiko isinku naa pe awọn oku miran ṣi wa ni ibudo ikọlu naa ti awọn eeyan agbegbe naa ko tii loore ọfẹ lati gbe pada wale nitori awọn eeyan ṣi wa ti wọn ṣi n wa bayii nibẹ.
 
Lati: BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI