USMAN JAHUN NI ADARI ẸGBẸ FIJILANTE, Ẹ MA F'ETI S'AYEDERU IROYIN - ILEEṢẸ VGN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 30, 2020

USMAN JAHUN NI ADARI ẸGBẸ FIJILANTE, Ẹ MA F'ETI S'AYEDERU IROYIN - ILEEṢẸ VGN

 
Ileeṣẹ eleto aabo ilu ati agbegbe, iyẹn Fijilante, Vigilante Group of Nigeria lorilẹ-ede Naijiria ti sọ pe Ọmọwe Usman Mohammed Jahun ni adari wọn, ko si sẹni to yọ ọ nipo kankan.
 
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ naa, eyi ti agbẹnusọ wọn lapapọ, Ọgbẹni Nureni Ọlanrewaju Adedoyin fi sita laipẹ yii lo ti sọ pe k'awọn araalu ma ṣe feti si ayederu ẹsun t'awọn kan ti wọn ko nifẹẹ alaafia fi kan ọga awọn.
 
Laipẹ yii ni wọn sọ pe atẹjade kan jade sita lati ọwọ ẹnikan to pe ara rẹ ni Umar Bakori, eyi ti iwe iroyin kan gbe wi pe wọn fẹsun jibiti ati ikowojẹ kan Usman Jahun, ti wọn si ni wọn ti da ọkunrin naa duro.
 
Ileeṣẹ VGN sọ pe atẹjade naa ki i ṣe lalti ọdọ awọn alakoso ẹgbẹ naa rara, ati pe awọn to n wa ki ẹgbẹ naa bajẹ ni wọn wa nidi atẹjade buruku naa, ti wọn si sọ pe k'awọn araalu ma ṣe gbagbọ.
 
Wọn ni gbogbo atẹjade ti ko ba ti jade lati olu-ileeṣẹ wọn to wa ni No 1 Ibrahim Gambari Crescent Katampe new extension Abuja lo jẹ ayederu nitori pe ibi t'awọn alaṣẹ naa n lo lati igba pipẹ ni.
 
Ninu atẹjade oni koko pataki mẹwa to tẹ AWIKONKO lọwọ ni wọn ti sọ ọ di mimọ pe:
*Atẹjade buruku naa ko jade lati ileeṣẹ VGN ti Ọmọwe Muhammed Jahun jẹ adari rẹ.
*Atẹjade naa jẹ eyi to n ṣi awọn araalu lọkan lati ba orukọ Usman Jahun ati agbẹnusọ, Ọlanrewaju Adedoyin jẹ.
*Ko s'igba kankan ti ẹsun ikowojẹ tabi ṣiṣẹ owo kumọkumọ jade sita, tabi pe wọn tọpinpin owo kan de ọdọ Usman Jahun.
*Ile ẹjọ kotẹmilọrun ninu iwe ipẹjọ CA:K/253/2018 ni wọn ti kede Usman Jahun gẹgẹ bi adari ẹgbẹ naa, ko si ni nnkan ṣe pẹlu Oloogbe Ali Ṣokoto bi o ṣe VGN lapapọ.
*Alaga alakoso ẹgbẹ naa, Alaaji Dalhatu ti fọwọ sọya lori Usman Jahun gẹgẹ bi adari ẹgbẹ naa.
*Ẹni to ṣagbatẹru atẹjade buruku naa ko si lara igbimọ alakoso, bẹẹ si ni ko si ninu ẹgbẹ VGN rara, orukọ lo n wa ni gbogbo ọna.
*Awọn alakoso ẹgbẹ VGN ko f'igba kankan da Usman Jahun duro gẹgẹ bi adari wọn.
*K'awọn araalu ma ṣe gba iroyin buruku naa gbọ rara, nitori pe irọ to jinna si otitọ lo kun inu ẹ.
*K'awọn ọmọ ẹgbẹ VGN kaakiri Naijiria ma ṣe ri atẹjade naa gẹgẹ bi i babara, dipo bẹẹ ki wọn maa ba iṣẹ wọn lọ pẹlu igbagbọ ninu Usman Jahun.
*Ẹni to ṣagbatẹru ayederu iroyin naa, iyẹn ẹni ti wọn pe ni Umar Bakori yẹ ko mọ daadaa n'igba to ba di ọrọ ileeṣẹ, ko si dẹkun lati maa pe ara rẹ ni adari tabi ọmọ ẹgbẹ VGN.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI